\id 2CH - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 \ide UTF-8 \h 2 Kronika \toc1 Ìwé Kronika Kejì \toc2 2 Kronika \toc3 2Ki \mt1 Ìwé Kronika Kejì \c 1 \s1 Solomoni béèrè fún ọgbọ́n \p \v 1 Solomoni ọmọ Dafidi fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọ́pọ̀. \p \v 2 Nígbà náà, Solomoni bá gbogbo Israẹli sọ̀rọ̀ sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Israẹli, àwọn olórí ìdílé \v 3 pẹ̀lú Solomoni, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gibeoni, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Mose ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* ti pa ní aginjù. \v 4 Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu. \v 5 Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe wà ní Gibeoni níwájú àgọ́ \nd Olúwa\nd*, bẹ́ẹ̀ ni Solomoni àti gbogbo àpéjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀. \v 6 Solomoni gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú \nd Olúwa\nd* ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹbọ sísun lórí rẹ̀. \p \v 7 Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Solomoni, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.” \p \v 8 Solomoni dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dafidi baba mi, ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \v 9 Nísinsin yìí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dafidi wá sí ìmúṣẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀. \v 10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè máa wọ ilé kí ń sì máa jáde níwájú ènìyàn wọ̀nyí, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?” \p \v 11 Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí. \v 12 Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.” \p \v 13 Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli. \p \v 14 Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu. \v 15 Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè. \v 16 Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan. \v 17 Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin méjìdínláàádọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu. \c 2 \s1 Àwọn ètò fún kíkọ́ ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ \nd Olúwa\nd* àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀ \v 2 Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn. \p \v 3 Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire: \pm “Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé. \v 4 Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé. \pm \v 5 “Ilé \nd Olúwa\nd* tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ. \v 6 Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún \nd Olúwa\nd*, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún \nd Olúwa\nd*, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀? \pm \v 7 “Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè. \pm \v 8 “Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ. \v 9 Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé \nd Olúwa\nd* tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀. \v 10 Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.” \p \v 11 Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni: \pm “Nítorí tí \nd Olúwa\nd* fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.” \p \v 12 Hiramu fi kún un pe, \pm “Ìyìn ni fún \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye, tí yóò kọ́ ilé fún \nd Olúwa\nd* àti ààfin fún ara rẹ̀. \pm \v 13 “Èmi ń rán Huramu-Abi, ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye sí ọ. \v 14 Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ. \pm \v 15 “Nísinsin yìí, jẹ́ kí olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní alikama àti barle àti òróró Olifi náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí. \v 16 Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.” \p \v 17 Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600). \v 18 Ó sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún (3,600) alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́. \c 3 \s1 Solomoni kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí \nd Olúwa\nd* ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè. \v 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. \p \v 3 Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́. \v 4 Ìloro tí ó wà níwájú ilé \nd Olúwa\nd* náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́. \p Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà. \v 5 Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n. \v 6 Ó ṣe ilé \nd Olúwa\nd* náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu. \v 7 Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri. \p \v 8 Ó kọ́ Ibi Mímọ́ Jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé \nd Olúwa\nd* mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára. \v 9 Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà. \p \v 10 Ní Ibi Mímọ́ Jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà. \v 11 Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé \nd Olúwa\nd*. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn. \v 12 Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé \nd Olúwa\nd* mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. \v 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá náà. \p \v 14 Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀. \p \v 15 Níwájú ilé \nd Olúwa\nd* náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. \v 16 Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rùn-ún pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà \v 17 Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé \nd Olúwa\nd*, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi. \c 4 \s1 Àwọn ìpèsè fún ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga. \v 2 Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀. \v 3 Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn. \p \v 4 Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín. \v 5 Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) bati dúró. \p \v 6 Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan. \p \v 7 Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé \nd Olúwa\nd* márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. \p \v 8 Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé \nd Olúwa\nd*, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà. \p \v 9 Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ. \v 10 Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá igun gúúsù àríwá. \p \v 11 Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. \p Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run. \b \li1 \v 12 Àwọn ọ̀wọ́n méjì; \li1 ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; \li1 àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n; \li1 \v 13 irinwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì náà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà; \li1 \v 14 ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn; \li1 \v 15 agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀; \li1 \v 16 àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fi ara pẹ́ ẹ. \b \p Gbogbo ohun èlò ti Huramu-Abi fi idẹ dídán ṣe fún Solomoni ọba, fún ilé \nd Olúwa\nd* jẹ́ idẹ dídán. \v 17 Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ní àárín méjì Sukkoti àti Sereda. \v 18 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Solomoni ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ́n. \p \v 19 Solomoni pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run: \b \li1 pẹpẹ wúrà \li1 tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀; \li1 \v 20 àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀; \li1 \v 21 pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn; \li1 \v 22 pẹ̀lú ọ̀pá fìtílà, àti àwokòtò àti ṣíbí àti àwokòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹmpili, àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn à bá wọ inú gbọ̀ngàn ńlá. \b \c 5 \p \v 1 Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ti ṣe fún tẹmpili \nd Olúwa\nd* ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀ṣọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Ọlọ́run. \s1 A gbé àpótí ẹ̀rí wọ inú tẹmpili \p \v 2 Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi. \v 3 Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́. \p \v 4 Gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli sì wá, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*. \v 5 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ni ó mú wọn gòkè wá. \v 6 Nígbà náà ni ọba Solomoni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò le è kà tán rú ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó. \p \v 7 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú \nd Olúwa\nd* wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé \nd Olúwa\nd*, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. \v 8 Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró. \v 9 Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí orí àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú Ibi Mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí. \v 10 Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe wàláà méjì tí Mose fi sínú rẹ̀ ní Horebu, ní ìgbà tí \nd Olúwa\nd* fi bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti. \p \v 11 Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti Ibi Mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn. \v 12 Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn. \v 13 Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun \nd Olúwa\nd*. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin \nd Olúwa\nd*, wọ́n ń kọrin pé, \q1 “Ó dára; \q2 ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.” \p Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili \nd Olúwa\nd*, \v 14 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò le è ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùùkuu náà, nítorí ògo \nd Olúwa\nd* kún inú tẹmpili Ọlọ́run. \c 6 \p \v 1 Nígbà náà ni Solomoni wí pé, “\nd Olúwa\nd* ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú òkùnkùn tí ó ṣú biribiri; \v 2 ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹmpili dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.” \p \v 3 Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn. \v 4 Nígbà náà ni ó sì wí pé: \pm “Ògo ni fún \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, \v 5 ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. \v 6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’ \pm \v 7 “Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ \nd Olúwa\nd*, àní Ọlọ́run Israẹli. \v 8 Ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀. \v 9 Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’ \pm \v 10 “\nd Olúwa\nd* sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli. \v 11 Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti \nd Olúwa\nd* bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.” \s1 Solomoni gba àdúrà ìyàsímímọ́ \p \v 12 Nígbà náà ni Solomoni dúró níwájú pẹpẹ \nd Olúwa\nd*, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. \v 13 Solomoni ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárín àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run. \v 14 Ó wí pé: \pm “\nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ. \v 15 Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí. \pm \v 16 “Nísinsin yìí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsi ara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’ \v 17 Nísinsin yìí, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi kí ó wá sí ìmúṣẹ. \pm \v 18 “Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́. Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé \nd Olúwa\nd* tí mo ti kọ́! \v 19 Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ. \v 20 Kí ojú rẹ kí ó lè ṣí sí ilé \nd Olúwa\nd* ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí. \v 21 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjì. \pm \v 22 “Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, \v 23 nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. \pm \v 24 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé \nd Olúwa\nd* yìí, \v 25 nígbà náà, ni kí o gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn. \pm \v 26 “Nígbà tí a bá ti ọ̀run, tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, \v 27 nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní. \pm \v 28 “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá. \v 29 Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé \nd Olúwa\nd* yìí. \v 30 Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn.) \v 31 Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa. \pm \v 32 “Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà pẹ̀lú kíkojú si ilé \nd Olúwa\nd* yìí. \v 33 Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́. \pm \v 34 “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé \nd Olúwa\nd* tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. \v 35 Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró. \pm \v 36 “Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, \v 37 ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’; \v 38 tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé \nd Olúwa\nd* tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ; \v 39 nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ. \pm \v 40 “Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí. \qm1 \v 41 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ, \qm2 ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. \qm1 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n láṣọ pẹ̀lú ìgbàlà, \qm2 jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ. \qm1 \v 42 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmì òróró rẹ. \qm2 Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ.” \c 7 \s1 Ìyàsímímọ́ ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Nígbà tí Solomoni sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ẹbọ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé \nd Olúwa\nd*. \v 2 Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé \nd Olúwa\nd* náà nítorí pé ògo \nd Olúwa\nd* kún un. \v 3 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo \nd Olúwa\nd* lórí ilé \nd Olúwa\nd* náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin \nd Olúwa\nd*, wọ́n sì fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd* wí pé, \q1 “Nítorí tí ó dára; \q2 àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.” \m \v 4 Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú \nd Olúwa\nd*. \v 5 Ọba Solomoni sì rú ẹbọ ti ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000), orí màlúù àti àgùntàn àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn àti ẹranko. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn ya ilé Ọlọ́run sí mímọ́. \v 6 Àwọn àlùfáà dúró ní ààyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin \nd Olúwa\nd*, tí ọba Dafidi ti ṣe fún ìyìn \nd Olúwa\nd* àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “Àánú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Lefi, àwọn àlùfáà sì fọn ìpè, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dúró. \p \v 7 Solomoni sì yà àgbàlá níwájú ilé \nd Olúwa\nd* sọ́tọ̀, níbẹ̀ sì ni ó ti ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà. \p \v 8 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lebo-Hamati títí dé odò Ejibiti. \v 9 Ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n sì pe ìjọ ènìyàn jọ nítorí tí wọ́n pe àpèjẹ ìyàsímímọ́ ti orí pẹpẹ fún ọjọ́ méje àti àsè náà fún ọjọ́ méje sí i. \v 10 Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù keje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí \nd Olúwa\nd* ti ṣe fún Dafidi àti Solomoni, àti fún àwọn ènìyàn Israẹli. \s1 \nd Olúwa\nd* fi ara han Solomoni \p \v 11 Nígbà tí Solomoni ti parí ilé \nd Olúwa\nd* àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé \nd Olúwa\nd* àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀, \v 12 \nd Olúwa\nd* sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: \pm “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ. \pm \v 13 “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi, \v 14 tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn. \v 15 Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí. \v 16 Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé. \pm \v 17 “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run, \v 18 Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli. \pm \v 19 “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n, \v 20 nígbà náà ni èmi yóò fa Israẹli tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrín gbogbo ènìyàn, \v 21 àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí \nd Olúwa\nd* fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’ \v 22 Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé, ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ” \c 8 \s1 Àwọn iṣẹ́ Solomoni mìíràn \p \v 1 Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* àti ilé òun fúnra rẹ̀. \v 2 Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀. \v 3 Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀. \v 4 Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati. \v 5 Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú. \v 6 Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí. \p \v 7 Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli, \v 8 èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí. \v 9 Ṣùgbọ́n Solomoni kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. \v 10 Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba (250) àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn. \p \v 11 Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.” \p \v 12 Lórí pẹpẹ \nd Olúwa\nd* tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí \nd Olúwa\nd*, \v 13 nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́. \v 14 Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ. \v 15 Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Lefi, nínú ohunkóhun, àti pẹ̀lú ti ìṣúra. \p \v 16 Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé \nd Olúwa\nd* lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé \nd Olúwa\nd* sì parí. \p \v 17 Nígbà náà ni Solomoni lọ sí Esioni-Geberi àti Elati ní Edomu létí òkun. \v 18 Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá. \c 9 \s1 Ọbabìnrin Ṣeba bẹ Solomoni wò \p \v 1 Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀. \v 2 Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún. \v 3 Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́, \v 4 oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé \nd Olúwa\nd*, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu. \p \v 5 Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni. \v 6 Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́. \v 7 Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ! \v 8 Ìyìn ló yẹ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.” \p \v 9 Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni. \p \v 10 Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá. \v 11 Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé \nd Olúwa\nd* àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda. \p \v 12 Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀. \s1 Dídán Solomoni \p \v 13 Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì, \v 14 láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni. \p \v 15 Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà. \v 16 Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni. \p \v 17 Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú eyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó. \v 18 Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn. \v 19 Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn. \v 20 Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. \v 21 Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí. \p \v 22 Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. \v 23 Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀. \v 24 Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá. \p \v 25 Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu. \v 26 Ó sì jẹ ọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò Eufurate títí dé ilé àwọn ará Filistini àti títí ó fi dé agbègbè ti Ejibiti. \v 27 Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. \v 28 A sì mú àwọn ẹṣin Solomoni wa láti ilẹ̀ òkèrè láti Ejibiti àti láti gbogbo ìlú. \s1 Ikú Solomoni \p \v 29 Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati? \v 30 Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún \v 31 Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \c 10 \s1 Israẹli sì ṣọ̀tẹ̀ lórí Rehoboamu \p \v 1 Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu nítorí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba. \v 2 Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti. \v 3 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránṣẹ́ sí Jeroboamu àti òun àti gbogbo àwọn Israẹli lọ sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu wọ́n sì wí fún pé, \v 4 “Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.” \p \v 5 Rehoboamu sì dáhùn pé, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ. \p \v 6 Nígbà náà ni ọba Rehoboamu fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbàgbà tí ó ti ń sin baba rẹ̀ Solomoni nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?” \p \v 7 Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ìre fún wọn, kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.” \p \v 8 Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbàgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbàsókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀. \v 9 Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’ ” \p \v 10 Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ. \v 11 Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’ ” \p \v 12 Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.” \v 13 Nígbà náà ni ọba dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Rehoboamu ọba sì kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbàgbà sílẹ̀, \v 14 Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.” \v 15 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo. \p \v 16 Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, \q1 “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, \q2 ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? \q1 Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! \q2 Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” \m Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn. \v 17 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ní ìlú Juda, Rehoboamu ń jẹ ọba lórí wọn. \p \v 18 Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu. \v 19 Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli sì wà ní ìṣọ̀tẹ̀ lórí ilé Dafidi títí fi di òní yìí. \c 11 \s1 \nd Olúwa\nd* Kọ̀ fún Juda láti Bá Israẹli Jagun \p \v 1 Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ilé Juda àti Benjamini jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Israẹli jà kí ó lè mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. \p \v 2 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé, \v 3 “Wí fún Rehoboamu ọmọ Solomoni ọba Juda, sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní Juda àti Benjamini, \v 4 ‘Èyí ní ohun tí \nd Olúwa\nd* wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ láti lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jeroboamu. \p \v 5 Rehoboamu ń gbe ní Jerusalẹmu ó sì kọ́ àwọn ìlú fún olódi ní Juda. \v 6 Bẹtilẹhẹmu, Etamu, Tekoa, \v 7 Beti-Suri, Soko, Adullamu, \v 8 Gati, Meraṣa Sifi, \v 9 Adoraimu, Lakiṣi, Aseka \v 10 Sora, Aijaloni, àti Hebroni. Wọ̀nyí ni àwọn ìlú ìdáàbòbò ní Juda àti Benjamini. \v 11 Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì. \v 12 Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀. \s1 Àwọn ọmọ Lefi dúró pẹ̀lú Juda \p \v 13 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákèjádò Israẹli wà ní ẹ̀bá rẹ̀. \v 14 Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà \nd Olúwa\nd*. \v 15 Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, àti fún àwọn ère òbúkọ, àti fún ẹgbọrọ màlúù tí ó ṣe. \v 16 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba a wọn. \v 17 Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí. \s1 Rehoboamu kó obìnrin jọ fún ara rẹ̀ \p \v 18 Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí. \v 19 Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jeuṣi, Ṣemariah àti Sahamu. \v 20 Nígbà náà, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, tí ó bí Abijah fún Attai, Sisa àti Ṣelomiti. \v 21 Rehoboamu fẹ́ràn Maaka ọmọbìnrin Absalomu ju èyíkéyìí nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin. \p \v 22 Rehoboamu yan Abijah ọmọ Maaka láti jẹ́ olóyè ọmọ-aládé láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba. \v 23 Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́n díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ká àwọn agbègbè Juda àti Benjamini àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn. \c 12 \s1 Ṣiṣaki gbógun ti Jerusalẹmu \p \v 1 Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ìjọba Rehoboamu múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Israẹli, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin \nd Olúwa\nd* tì. \v 2 Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí \nd Olúwa\nd*. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu. \v 3 Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti. \v 4 Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó. \p \v 5 Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.” \p \v 6 Àwọn olórí Israẹli àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni \nd Olúwa\nd*.” \p \v 7 Nígbà tí \nd Olúwa\nd* rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki. \v 8 Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.” \p \v 9 Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé \nd Olúwa\nd*, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá. \v 10 Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́. \v 11 Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé \nd Olúwa\nd*, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́. \p \v 12 Nítorí ti Rehoboamu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú \nd Olúwa\nd* yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì pa á run pátápátá. Nítòótọ́, ìre díẹ̀ wà ní Juda. \p \v 13 Ọba Rehoboamu fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jerusalẹmu, ó sì tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí \nd Olúwa\nd* ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Ammoni. \v 14 O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra nínú ọkàn rẹ̀ láti wá \nd Olúwa\nd*. \p \v 15 Fún tí iṣẹ́ ìjọba Rehoboamu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Ṣemaiah wòlíì àti ti Iddo, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀síwájú ogun jíjà sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu. \v 16 Rehoboamu sun pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi. Abijah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \c 13 \s1 Abijah ọba Juda \p \v 1 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jeroboamu, Abijah di ọba Juda. \v 2 Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah. \p Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. \v 3 Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára. \p \v 4 Abijah dúró lórí òkè Semaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi! \v 5 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀? \v 6 Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀. \v 7 Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n. \p \v 8 “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba \nd Olúwa\nd*, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín. \v 9 Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà \nd Olúwa\nd* jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run. \p \v 10 “Ní ti àwa, \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin \nd Olúwa\nd* jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. \v 11 Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú \nd Olúwa\nd*. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. \v 12 Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, ẹ má ṣe dojú ìjà kọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.” \p \v 13 Nísinsin yìí, Jeroboamu ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà níwájú Juda, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn. \v 14 Nígbà tí Juda sì bojú wo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwájú àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe \nd Olúwa\nd*, àwọn àlùfáà sì fun ìpè. \v 15 Olúkúlùkù, ọkùnrin Juda sì fún ìpè ogun, ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Juda sì ti fun ìpè ogun, ni Ọlọ́run kọlu Jeroboamu àti gbogbo Israẹli níwájú Abijah àti Juda. \v 16 Àwọn ọmọ Israẹli sálọ kúrò níwájú Juda, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́. \v 17 Abijah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ìdààmú ńlá jẹ wọ́n ní ìyà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ọkùnrin tí a yàn ṣubú ní pípa nínú Israẹli. \v 18 Báyìí ni a rẹ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ ní àkókò náà, àwọn ọmọ Juda sì borí nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wọn. \p \v 19 Abijah sì lépa Jeroboamu, ó sì gba ìlú lọ́wọ́ rẹ̀, Beteli pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Jeṣana pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀, àti Efroni pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀. \v 20 Bẹ́ẹ̀ ní Jeroboamu kò sì tún ní agbára mọ́ ní ọjọ́ Abijah. \nd Olúwa\nd* sì lù ú ó sì kú. \p \v 21 Abijah sì di alágbára, ó sì gbé obìnrin mẹ́tàlá ní ìyàwó, ó sì bi ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún. \p \v 22 Àti ìyókù ìṣe Abijah, àti ìwà rẹ̀, àti iṣẹ́ rẹ̀, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtumọ̀, wòlíì Iddo. \c 14 \s1 Asa ọba Juda \p \v 1 Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀-èdè wà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá. \p \v 2 Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó sì tọ́ ní ojú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. \v 3 Ó gbé àwọn pẹpẹ àjèjì kúrò àti àwọn ibi gíga. Ó fọ́ àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀, ó sì gé àwọn ère Aṣerah bolẹ̀. \v 4 Ó pa á láṣẹ fún Juda láti wá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba a wọn àti láti tẹ̀lé àwọn òfin rẹ̀ àti àṣẹ. \v 5 Ó gbé àwọn ibi gíga kúrò àti àwọn pẹpẹ tùràrí ní gbogbo ìlú ní Juda. Ìjọba sì wà ní àlàáfíà ní abẹ́ rẹ̀. \v 6 Ó mọ àwọn ìlú ààbò ti Juda, níwọ̀n ìgbà tí ìlú ti wà ní àlàáfíà. Kò sí ẹnikẹ́ni ti o jagun pẹ̀lú rẹ̀ nígbà náà, nítorí \nd Olúwa\nd* fún un ní ìsinmi. \p \v 7 “Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí,” ó wí fún Juda, “kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu-ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere. \p \v 8 Asa ní àwọn ọmọ-ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Juda. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Benjamini wọ́n dira pẹ̀lú àwọn àpáta kéékèèké àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin. \p \v 9 Sera ará Etiopia yàn láti dojúkọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Meraṣa. \v 10 Asa jáde lọ láti lọ bá a. Wọ́n sì mú ibi ogun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Sefata lẹ́bàá Meraṣa. \p \v 11 Nígbà náà, Asa ké pe \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “\nd Olúwa\nd* kò sí ẹnìkan bí rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́ láti dójú kọ alágbára. Ràn wá lọ́wọ́, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. \nd Olúwa\nd*, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.” \p \v 12 \nd Olúwa\nd* lu àwọn ará Kuṣi bolẹ̀ níwájú Asa àti Juda. Àwọn ará Kuṣi sálọ. \v 13 Asa àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gerari. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kuṣi ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. Wọn rún wọn mọ́lẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* àti ọmọ-ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Juda kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun. \v 14 Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gerari, nítorí tí ìpayà \nd Olúwa\nd* ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn. Wọ́n kó gbogbo ìkógun àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀. \v 15 Wọ́n kọlu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jerusalẹmu. \c 15 \s1 Àtúnṣe asà \p \v 1 Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Asariah ọmọ Odedi. \v 2 Ó jáde lọ bá Asa, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Asa, àti gbogbo Juda àti Benjamini. \nd Olúwa\nd* wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. \v 3 Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Israẹli ti wà láì sin Ọlọ́run òtítọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láìní òfin. \v 4 Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn. \v 5 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá. \v 6 Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlú kan sí òmíràn nítorí Ọlọ́run ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú. \v 7 Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì ṣe ṣàárẹ̀. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ.” \p \v 8 Nígbà tí Asa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Asariah ọmọ Odedi wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó sì mú gbogbo ohun ìríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda àti Benjamini àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní orí òkè Efraimu. Ó tún pẹpẹ \nd Olúwa\nd* ṣe tí ó wà ní iwájú portiko ti ilé \nd Olúwa\nd*. \p \v 9 Nígbà náà, ó pe gbogbo Juda àti Benjamini jọ àti àwọn ènìyàn láti Efraimu, Manase àti Simeoni tí ó ti ṣe àtìpó ní àárín wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Israẹli nígbà tí wọ́n rí i wí pé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. \p \v 10 Wọ́n péjọ sí Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹ́ẹ̀dógún ti ìjọba Asa. \v 11 Ní àkókò yìí, wọ́n rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd* ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkógun tí wọ́n ti kó padà. \v 12 Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn. \v 13 Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin. \v 14 Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún \nd Olúwa\nd* àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè. \v 15 Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, \nd Olúwa\nd* sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri. \p \v 16 Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní àfonífojì Kidironi. \v 17 Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Israẹli; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Asa wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. \v 18 Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà. \p \v 19 Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùndínlógójì ti ìjọba Asa. \c 16 \s1 Ìgbẹ̀yìn ọdún asà \p \v 1 Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ. \p \v 2 Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé \nd Olúwa\nd* àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, \v 3 “Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” \p \v 4 Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. \v 5 Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. \v 6 Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa. \p \v 7 Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. \v 8 Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé \nd Olúwa\nd* yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. \v 9 Nítorí ojú \nd Olúwa\nd* yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.” \p \v 10 Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára. \p \v 11 Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. \v 12 Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. \v 13 Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, \v 14 wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀. \c 17 \s1 Jehoṣafati ọba Juda \p \v 1 Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ ó sì mú ara rẹ̀ lágbára sí lórí Israẹli. \v 2 Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Juda ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Juda àti nínú ìlú Efraimu tí Asa baba rẹ̀ ti gbà. \p \v 3 \nd Olúwa\nd* sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali. \v 4 Ṣùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Israẹli. \v 5 \nd Olúwa\nd* sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀. \v 6 Ọkàn rẹ̀ sì gbé sókè si ọ̀nà \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lúpẹ̀lú, ó sì mú ibi gíga wọn àti ère òrìṣà Aṣerah kúrò ní Juda. \p \v 7 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bene-Haili, Obadiah, Sekariah, Netaneli, Mikaiah láti máa kọ́ ni nínú ìlú Juda. \v 8 Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi, àní Ṣemaiah, Netaniah, Sebadiah, Asaheli, Ṣemiramotu, Jehonatani, Adonijah, Tobijah àti Tobu-Adonijah àti àwọn àlùfáà Eliṣama àti Jehoramu. \v 9 Wọ́n ń kọ́ ni ní agbègbè Juda, wọ́n mú ìwé òfin \nd Olúwa\nd* wọ́n sì rìn yíká gbogbo àwọn ìlú Juda wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn. \p \v 10 Ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Juda ká, dé bi pé wọn kò bá Jehoṣafati jagun. \v 11 Lára àwọn ará Filistini, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jehoṣafati, àwọn ará Arabia sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún un, ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) àgbò àti ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) òbúkọ. \p \v 12 Jehoṣafati sì ń di alágbára nínú agbára sí i, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìṣúra púpọ̀ ní Juda \v 13 Ó sì ní ìṣúra ní ìlú Juda. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jerusalẹmu. \v 14 Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nìwọ̀nyí. \b \li1 Láti Juda, àwọn olórí ìpín kan ti ẹgbẹ̀rún (1,000): \li2 Adina olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) alágbára akọni ọkùnrin. \li2 \v 15 Èkejì, Jehohanani olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) ọkùnrin; \li2 \v 16 àtẹ̀lé Amasiah ọmọ Sikri, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). \li1 \v 17 Láti ọ̀dọ̀ Benjamini: \li2 Eliada, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra; \li2 \v 18 àtẹ̀lé Jehosabadi, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun. \b \m \v 19 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwájú ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Juda. \c 18 \s1 Mikaiah sọtẹ́lẹ̀ lórí Ahabu \p \v 1 Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. \v 2 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi. \v 3 Ahabu ọba Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jehoṣafati, ọba Juda pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Ramoti Gileadi?” \p Jehoṣafati sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ nínú ogun náà”. \v 4 Ṣùgbọ́n Jehoṣafati náà sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*.” \p \v 5 Bẹ́ẹ̀ ọba Israẹli kó àwọn wòlíì papọ̀, irinwó (400) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Ramoti Gileadi tàbí kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?” \p Wọ́n dáhùn pé, “Lọ, nítorí tí Ọlọ́run yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” \p \v 6 Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ṣé kò ha sí wòlíì \nd Olúwa\nd* níbí ẹni tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” \p \v 7 Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ìbá tún béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorí kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Mikaiah ọmọ Imla.” \p Jehoṣafati sì dá lóhùn pé, “Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” \p \v 8 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pe ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ó sì wí pé, “Ẹ mú Mikaiah ọmọ Imla kí ó yára wá.” \p \v 9 Wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn, ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọ́n ní ìta ẹnu-bodè Samaria, pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn. \v 10 Nísinsin yìí Sedekiah ọmọ Kenaana sì ti ṣe ìwo irin, ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ: ‘Pẹ̀lú èyí ìwọ yóò kan àwọn ará Siria títí ìwọ ó fi pa wọ́n run.’ ” \p \v 11 Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò kan náà. Wọ́n sì wí pé, “Dojúkọ Ramoti Gileadi ìwọ yóò sì ṣẹ́gun, nítorí \nd Olúwa\nd* yóò fi lé ọba lọ́wọ́.” \p \v 12 Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.” \p \v 13 Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé \nd Olúwa\nd* ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.” \p \v 14 Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Mikaiah, ṣe kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Ramoti Gileadi, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?” \p Ó sì dáhùn pé, “Ẹ dojúkọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun, nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” \p \v 15 Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ \nd Olúwa\nd*?” \p \v 16 Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, \nd Olúwa\nd* sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ” \p \v 17 Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?” \p \v 18 Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*, mo rí \nd Olúwa\nd* jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. \v 19 \nd Olúwa\nd* sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’ \p “Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. \v 20 Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú \nd Olúwa\nd* ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ \p “ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ \nd Olúwa\nd* béèrè. \p \v 21 “ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’ \p “ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni \nd Olúwa\nd* wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ \p \v 22 “Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí \nd Olúwa\nd* ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. \nd Olúwa\nd* sì ti sọ ibi sí ọ.” \p \v 23 Nígbà náà Sedekiah ọmọ Kenaana lọ sókè ó sì gbá Mikaiah ní ojú. Ó sì béèrè pé, “Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí \nd Olúwa\nd* gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” \p \v 24 Mikaiah sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò ṣe ìwádìí ní ọjọ́ tí ìwọ yóò sá pamọ́ sínú ìyẹ̀wù.” \p \v 25 Ọba Israẹli pa á láṣẹ pé, “Mú Mikaiah kí o sì ran padà sí Amoni olórí ìlú àti sí Joaṣi ọmọ ọba, \v 26 Ó sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ, ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ” \p \v 27 Mikaiah sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, \nd Olúwa\nd* kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún un pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!” \s1 A pa Ahabu ní Ramoti Gileadi \p \v 28 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda lọ sókè ní Ramoti Gileadi. \v 29 Ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ rẹ̀ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà. \p \v 30 Nísinsin yìí ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ má ṣe jà pẹ̀lú ẹnìkankan, èwe tàbí àgbà àyàfi ọba Israẹli.” \v 31 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rí Jehoṣafati, wọ́n rò wí pé, “Èyí ní ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yípadà láti bá a jà. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati kégbe sókè, \nd Olúwa\nd* sì ràn án lọ́wọ́. Ọlọ́run sì lé wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, \v 32 Ó sì ṣe, nígbà tí olórí kẹ̀kẹ́ rí i wí pé kì í ṣe ọba Israẹli, wọ́n sì dáwọ́ lílé rẹ̀ dúró. \p \v 33 Ṣùgbọ́n ẹnìkan fa ọrun rẹ̀ láì pète, ó sì bá ọba Israẹli láàrín ìpàdé ẹ̀wù irin, ọba sì sọ fún olùtọ́jú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ pé, “Yí ọwọ́ rẹ padà, kí o sì wà mí jáde kúrò lójú ìjà. Nítorí èmi ti gbọgbẹ́.” \v 34 Ní ọjọ́ pípẹ́, ìjà náà sì ń pọ̀ sí i, ọba Israẹli dúró nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kọjú sí àwọn ará Siria títí ó fi di àṣálẹ́. Lẹ́yìn náà ní àkókò ìwọ oòrùn, ó sì kú. \c 19 \s1 Jehu bá Jehoṣafati wí \p \v 1 Nígbà tí Jehoṣafati ọba Juda padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu, \v 2 Jehu aríran, ọmọ Hanani jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Ṣé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra \nd Olúwa\nd*? Nítorí èyí, ìbínú \nd Olúwa\nd* wà lórí wa. \v 3 Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà Aṣerah kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.” \s1 Jehoṣafati yan àwọn onídàájọ́ \p \v 4 Jehoṣafati sì ń gbé ní Jerusalẹmu ó sì jáde lọ padà láàrín àwọn ènìyàn láti Beerṣeba dé òkè ìlú Efraimu, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba wọn. \v 5 Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi Juda. \v 6 Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsi ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún \nd Olúwa\nd*, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́. \v 7 Nísinsin yìí jẹ́ kí ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd* kí ó wá sí ọkàn rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” \p \v 8 Ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, Jehoṣafati yan díẹ̀ lára àwọn Lefi, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Israẹli si pípa òfin \nd Olúwa\nd* mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jerusalẹmu. \v 9 Ó sì kìlọ̀ fún wọn wí pé. “Ìwọ gbọdọ̀ sìn pẹ̀lú òtítọ́ àti pẹ̀lú ọkàn pípé ní ìbẹ̀rù \nd Olúwa\nd*. \v 10 Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń sàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, pa á láṣẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí \nd Olúwa\nd* bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyí, ìwọ kì yóò sì jẹ̀bi. \p \v 11 “Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti \nd Olúwa\nd*, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, \nd Olúwa\nd* yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.” \c 20 \s1 Jehoṣafati pa Moabu àti Amoni run \p \v 1 Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati. \p \v 2 Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe En-Gedi). \v 3 Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. \v 4 Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd*; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a. \p \v 5 Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé \nd Olúwa\nd* níwájú àgbàlá tuntun. \v 6 O sì wí pé, \pm “\nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. \v 7 Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? \v 8 Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, \v 9 ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’ \pm \v 10 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. \v 11 Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní. \v 12 Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.” \p \v 13 Gbogbo àwọn ọkùnrin Juda, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kéékèèké, dúró níbẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd*. \p \v 14 Nígbà náà, ẹ̀mí \nd Olúwa\nd* sì bà lé Jahasieli ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah ọmọ Lefi àti ọmọ Asafu, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrín àpéjọ ènìyàn. \p \v 15 Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jehoṣafati àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Juda àti Jerusalẹmu! Èyí ní ohun tí \nd Olúwa\nd* sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí ogun náà kì í ṣe tiyín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni. \v 16 Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli. \v 17 Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. ẹ dúró ní ààyè yín; ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà \nd Olúwa\nd* tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, \nd Olúwa\nd* yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ” \p \v 18 Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin \nd Olúwa\nd*. \v 19 Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ọmọ Kohati àti àwọn ọmọ Kora sì dìde dúró wọ́n sì sin \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá. \p \v 20 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí aginjù Tekoa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jehoṣafati dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ mi, Juda àti ènìyàn Jerusalẹmu! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.” \v 21 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí \nd Olúwa\nd* àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé, \q1 “Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, \q2 nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.” \p \v 22 Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, \nd Olúwa\nd* rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n. \v 23 Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run. \p \v 24 Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá. \v 25 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀. \v 26 Ní ọjọ́ kẹrin, wọn kó ara jọ pọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún \nd Olúwa\nd*. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní. \p \v 27 Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí \nd Olúwa\nd* ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. \v 28 Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè. \p \v 29 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí \nd Olúwa\nd* ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà. \v 30 Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká. \s1 Òpin ìjọba Jehoṣafati \p \v 31 Báyìí ni Jehoṣafati jẹ ọba lórí Juda. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. \v 32 Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Asa kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú \nd Olúwa\nd*. \v 33 Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lú, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkàn wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn. \p \v 34 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoṣafati, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jehu ọmọ Hanani, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Israẹli. \p \v 35 Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati ọba Juda da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Ahasiah, ọba Israẹli, ẹni tí ó jẹ̀bi ìwà búburú. \v 36 Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan ọkọ̀ láti lọ sí Tarṣiṣi, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Esioni-Geberi. \v 37 Elieseri ọmọ Dodafahu ti Meraṣa sọtẹ́lẹ̀ sí Jehoṣafati, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, \nd Olúwa\nd* yóò pa ohun ti ìwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà. \c 21 \p \v 1 Nígbà náà Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \v 2 Àwọn arákùnrin Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jẹ́ Asariah, Jehieli, Sekariah. Asariahu, Mikaeli àti Ṣefatia. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jehoṣafati ọba Israẹli. \v 3 Baba wọn ti fún wọn ní ẹ̀bùn púpọ̀ ti fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò iyebíye pẹ̀lú àwọn ìlú ààbò ní Juda, ṣùgbọ́n, ó ti gbé ìjọba fún Jehoramu nítorí òun ni àkọ́bí ọmọkùnrin. \s1 Jehoramu ọba Juda \p \v 4 Nígbà tí Jehoramu fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ gidigidi lórí ìjọba baba a rẹ̀, ó sì fi idà pa gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli. \v 5 Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. \v 6 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Ahabu. Ó ṣe búburú lójú \nd Olúwa\nd*. \v 7 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí \nd Olúwa\nd* ti dá fún Dafidi kì í ṣe ìfẹ́ \nd Olúwa\nd* láti pa ìdílé Dafidi run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé. \p \v 8 Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀. \v 9 Bẹ́ẹ̀ ni, Jehoramu lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́. Àwọn ará Edomu yí i ká àti àwọn alákòóso àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dìde ní òru ó sì ṣẹ́gun wọn ní òru. \v 10 Títí di ọjọ́ òní ni Edomu ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Juda. \p Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jehoramu ti kọ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀. \v 11 Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ. \p \v 12 Jehoramu gba ìwé láti ọwọ́ Elijah wòlíì, tí ó wí pé, \pm “Èyí ní ohun tí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run baba à rẹ Dafidi wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jehoṣafati tàbí Asa ọba Juda. \v 13 Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, ìwọ sì ti tọ́ Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé baba à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ. \v 14 Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí, \nd Olúwa\nd* ti fẹ́rẹ lu àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn ńlá. \v 15 Ìwọ tìkára yóò ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú àìsàn lílọ́ra ti ìfun, títí tí àìsàn náà yóò fi jẹ́ kí àwọn ìfun rẹ jáde sí ìta.’ ” \p \v 16 \nd Olúwa\nd* ru ìbínú àwọn ará Filistini àti àwọn Arabia tí wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá àwọn ará Kuṣi sí Jehoramu. \v 17 Wọ́n dojú ìjà kọ Juda, wọ́n gbà á, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Ahasiah, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀. \p \v 18 Lẹ́yìn gbogbo èyí, \nd Olúwa\nd* jẹ Jehoramu ní yà pẹ̀lú ààrùn tí kò ṣe é wòsàn nínú ìfun. \v 19 Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí ààrùn náà ó sì kú nínú ìrora ńlá. Àwọn ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bu ọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀. \p \v 20 Jehoramu jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dafidi. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba. \c 22 \s1 Ahasiah ọba Juda \p \v 1 Àwọn ènìyàn Jerusalẹmu mú Ahasiah, ọmọ Jehoramu tí ó kéré jùlọ, jẹ ọba ní ipò rẹ̀, láti ìgbà tí àwọn onísùnmọ̀mí, tí ó wá pẹ̀lú àwọn ará Arabia sínú ibùdó, tí wọn sì ti pa àwọn ọmọkùnrin àgbà. Bẹ́ẹ̀ ni Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. \p \v 2 Ahasiah jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún kan. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Ataliah, ọmọ ọmọbìnrin Omri. \p \v 3 Ó mú ìrìn ní ọ̀nà ilé Ahabu. Nítorí tí ìyá rẹ̀ kì í láyà nínú ṣíṣe búburú. \v 4 Ó ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ilé Ahabu ti ṣe, nítorí lẹ́yìn ikú baba a rẹ̀, wọ́n di olùgbani nímọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀. \v 5 Ó tẹ̀lé ìgbìmọ̀ wọn nígbà tí ó lọ pẹ̀lú Joramu ọmọ Ahabu ọba Israẹli láti gbógun ti Hasaeli ọba Aramu ní Ramoti Gileadi. Àwọn ará Aramu ṣá Joramu ní ọgbẹ́; \v 6 bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rama ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Siria. \p Nígbà náà, Ahasiah, ọmọ Jehoramu ọba Juda lọ sí Jesreeli láti lọ rí Joramu ọmọ Ahabu nítorí a ti ṣá a lọ́gbẹ́. \p \v 7 Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Ahasiah sí Joramu, Ọlọ́run mú ìṣubú Ahasiah wá. Nígbà tí Ahasiah dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jehoramu láti lọ bá Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí \nd Olúwa\nd* ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Ahabu run. \v 8 Nígbà tí Jehu ń ṣe ìdájọ́ lórí ilé Ahabu, ó rí àwọn ọmọbìnrin ọba ti Juda àti àwọn ọmọkùnrin ìbátan Ahasi, tí ó ń tọ́jú Ahasiah, ó sì pa wọ́n. \v 9 Ó lọ láti wá Ahasiah, àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. Àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀ nígbà tí ó sá pamọ́ ní Samaria. A gbé e wá sí ọ̀dọ̀ Jehu, a sì pa á. Wọ́n sin ín nítorí wọ́n wí pé, “Ọmọkùnrin Jehoṣafati ni, ẹni tí ó wá \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan ní ilé Ahasiah tí ó lágbára láti gbé ìjọba náà dúró. \s1 Ataliah àti Joaṣi \p \v 10 Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba ti ilẹ̀ Juda run. \v 11 Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu mú Joaṣi, ọmọkùnrin Ahasiah ó sì jí gbé lọ kúrò láàrín àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti ìyàwó àlùfáà Jehoiada jẹ́ arábìnrin Ahasiah. Ó fi ọmọ náà pamọ́ kúrò fún Ataliah, kí ó má ba à pa á. \v 12 Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú wọn ni ilé Ọlọ́run fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah ṣàkóso ilẹ̀ náà. \c 23 \p \v 1 Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri. \v 2 Wọ́n lọ sí gbogbo Juda, wọ́n sì pe àwọn ará Lefi àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Israẹli láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu. \v 3 Gbogbo ìpéjọ náà dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run. \p Jehoiada wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jẹ ọba, bí \nd Olúwa\nd* ti ṣèlérí nípa àwọn ìran Dafidi. \v 4 Nísinsin yìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe, ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Lefi tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn. \v 5 Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé \nd Olúwa\nd*. \v 6 Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé \nd Olúwa\nd* yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítorí tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó sọ ohun tí \nd Olúwa\nd* ti yàn fún wọn. \v 7 Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé \nd Olúwa\nd* ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.” \p \v 8 Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀. \v 9 Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún. \v 10 Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà. \p \v 11 Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!” \p \v 12 Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé \nd Olúwa\nd*. \v 13 Ó sì wò, sì kíyèsi, ọba dúró ní ibùdó rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afùnpè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn. Nígbà náà ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!” \p \v 14 Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé, “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé \nd Olúwa\nd*.” \v 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ẹṣin ti ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀. \p \v 16 Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn \nd Olúwa\nd*. \v 17 Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ. \p \v 18 Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé \nd Olúwa\nd* sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé \nd Olúwa\nd* láti tẹ ẹbọ sísun ti \nd Olúwa\nd* bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ. \v 19 Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé \nd Olúwa\nd* kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé. \p \v 20 Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé \nd Olúwa\nd*. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́. \v 21 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, ìlú náà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà. \c 24 \s1 Joaṣi tún ilé \nd Olúwa\nd* ṣe \p \v 1 Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibia ti Beerṣeba. \v 2 Joaṣi ṣe ohun tí ó dára ní ojú \nd Olúwa\nd* ní gbogbo àkókò Jehoiada àlùfáà. \v 3 Jehoiada yan ìyàwó méjì fún un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. \p \v 4 Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé \nd Olúwa\nd* ṣe. \v 5 Ó pe àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo Israẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe.” Ṣùgbọ́n àwọn ará Lefi kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà. \p \v 6 Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún Jehoiada olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Lefi láti mú wá láti Juda àti Jerusalẹmu, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Israẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?” \p \v 7 Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni Ataliah ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Baali. \p \v 8 Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé \nd Olúwa\nd*. \v 9 A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún \nd Olúwa\nd*, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ \nd Olúwa\nd* ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù. \v 10 Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mú un wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún. \v 11 Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Lefi sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá. \v 12 Ọba àti Jehoiada fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé \nd Olúwa\nd*. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé \nd Olúwa\nd* ṣe. \p \v 13 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le. \v 14 Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jehoiada, a sì fi ohun èlò fún ilé \nd Olúwa\nd*, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àní ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé \nd Olúwa\nd* nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jehoiada. \s1 Ikú Jehoiada \p \v 15 Ṣùgbọ́n Jehoiada di arúgbó, ó sì kún fún ọjọ́, ó sì kú, ẹni àádóje ọdún ni nígbà tí ó kú. \v 16 Wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi pẹ̀lú àwọn ọba, nítorí tí ó ṣe rere ní Israẹli, àti sí Ọlọ́run àti sí ilé rẹ̀. \s1 Ìwà búburú Joaṣi \p \v 17 Lẹ́yìn ikú Jehoiada, àwọn oníṣẹ́ Juda wá láti fi ìforíbalẹ̀ wọn hàn sí ọba. Ó sì fèsì sí wọn. \v 18 Wọ́n pa ilé \nd Olúwa\nd* tì, Ọlọ́run baba a wọn. Wọ́n sì ń sin àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yìí, ìbínú Ọlọ́run dé sórí Juda àti Jerusalẹmu. \v 19 Bí ó ti wù kí ó rí, \nd Olúwa\nd* rán àwọn wòlíì sí àwọn ènìyàn láti mú wọn padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, wọ́n jẹ́rìí nípa wọn, wọn kì yóò gbọ́. \p \v 20 Nígbà náà, Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Sekariah ọmọ Jehoiada wòlíì, ó dúró níwájú àwọn ènìyàn ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí: ‘Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tẹ̀lé àṣẹ \nd Olúwa\nd*? Ìwọ kì yóò ṣe rere. Nítorí tí ìwọ ti kọ \nd Olúwa\nd* sílẹ̀, òun pẹ̀lú ti kọ̀ yín sílẹ̀.’ ” \p \v 21 Ṣùgbọ́n wọ́n dìtẹ̀ sí i, àti nípa àṣẹ ọba, wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa nínú àgbàlá ààfin ilé \nd Olúwa\nd*. \v 22 Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Sakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí \nd Olúwa\nd* kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.” \p \v 23 Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun Aramu yàn láti dojúkọ Joaṣi; wọ́n gbógun ti Juda àti Jerusalẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Damasku. \v 24 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun Aramu ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ \nd Olúwa\nd* sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Juda ti kọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Joaṣi. \v 25 Nígbà tí àwọn ará Aramu kúrò, wọ́n fi Joaṣi sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọgbẹ́. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ si fún pípa ọmọ Jehoiada àlùfáà, wọ́n sì pa á ní orí ibùsùn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, a sì sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú àwọn ibojì àwọn ọba. \p \v 26 Àwọn tí ó dìtẹ̀ sì jẹ́ Sabadi, ọmọ Ṣimeati arábìnrin Ammoni àti Jehosabadi ọmọ Ṣimiriti arábìnrin Moabu. \v 27 Àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, àti àkọsílẹ̀ ti ìmúpadà sípò ilé Ọlọ́run ní a kọ sínú ìwé ìtumọ̀ ti àwọn ọba. Amasiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \c 25 \s1 Amasiah ọba Juda \p \v 1 Amasiah jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani, ó wá láti Jerusalẹmu. \v 2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú \nd Olúwa\nd*, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn. \v 3 Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba. \v 4 Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí \nd Olúwa\nd* ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” \p \v 5 Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú. \v 6 Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà. \p \v 7 Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́ ogun láti Israẹli kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí \nd Olúwa\nd* kò wà pẹ̀lú Israẹli kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Efraimu. \v 8 Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.” \p \v 9 Amasiah sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́ ogun àwọn ọmọ Israẹli ń kọ́?” \p Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “\nd Olúwa\nd* lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.” \p \v 10 Bẹ́ẹ̀ ni Amasiah, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Efraimu ká. Ó sì rán wọn lọ ilé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Juda, wọ́n sì padà lọ ilé pẹ̀lú ìbínú ńlá. \p \v 11 Nígbà náà, Amasiah ko ogun rẹ jọ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lọ sí àfonífojì iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Seiri. \v 12 Àwọn ọkùnrin Juda pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láààyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́. \p \v 13 Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Amasiah ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Juda láti Samaria sí Beti-Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá. \p \v 14 Nígbà tí Amasiah padà láti ibi pípa àwọn ará Edomu, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn Seiri padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rú ẹbọ fún wọn. \v 15 Ìbínú \nd Olúwa\nd* ru sí Amasiah, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn tiwọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?” \p \v 16 Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgba ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?” \p Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.” \p \v 17 Lẹ́yìn tí Amasiah ọba Juda ti béèrè lọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá bá mi lójúkojú.” \p \v 18 Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “Koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀. \v 19 Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?” \p \v 20 Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu. \v 21 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda. \v 22 Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀. \v 23 Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. \v 24 Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria. \p \v 25 Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. \v 26 Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Amasiah láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli? \v 27 Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé \nd Olúwa\nd*, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀. \v 28 A gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Juda. \c 26 \s1 Ussiah ọba Juda \p \v 1 Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. \v 2 Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. \p \v 3 Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. \v 4 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. \v 5 Ó sì wá \nd Olúwa\nd* ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run fún un ní ohun rere. \p \v 6 Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. \v 7 Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. \v 8 Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá. \p \v 9 Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le \v 10 Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe. \p \v 11 Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. \v 12 Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). \v 13 Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. \v 14 Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. \v 15 Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára. \p \v 16 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé \nd Olúwa\nd* láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. \v 17 Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà \nd Olúwa\nd* mìíràn sì tẹ̀lé e. \v 18 Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí \nd Olúwa\nd*. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run.” \p \v 19 Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé \nd Olúwa\nd*, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. \v 20 Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí \nd Olúwa\nd* ti kọlù ú. \p \v 21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé \nd Olúwa\nd*. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. \p \v 22 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ussiah láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. \v 23 Ussiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “Ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀,” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \c 27 \s1 Jotamu ọba Juda \p \v 1 Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. \v 2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé \nd Olúwa\nd*. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn. \v 3 Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé \nd Olúwa\nd* ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli. \v 4 Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi. \p \v 5 Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) òsùwọ̀n alikama àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta. \p \v 6 Jotamu sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tó tọ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. \p \v 7 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jotamu, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti ti Juda. \v 8 Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. \v 9 Jotamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \c 28 \s1 Ahasi ọba Juda \p \v 1 Ahasi sì jẹ́ ẹni ogún ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Gẹ́gẹ́ bí i Dafidi baba rẹ̀ kò sì ṣe ohun rere ní ojú \nd Olúwa\nd*. \v 2 Ó sì rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli ó sì ṣe ère dídá fún ìsìn Baali \v 3 Ó sì sun ẹbọ ní àfonífojì Hinnomu, ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli \v 4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọ́n nì lórí òkè kékeré àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. \p \v 5 Nítorí náà, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀ fi lé ọba Siria lọ́wọ́. Àwọn ará Siria sì pa á run, wọ́n sì kó púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, wọ́n sì kó wọn wá sí Damasku. \p Ó sì tún fi lé ọwọ́ ọba Israẹli pẹ̀lú, ẹni tí ó kó wọn ní ìgbèkùn púpọ̀ tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. \v 6 Ní ọjọ́ kan Peka, ọmọ Remaliah, pa ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àwọn ọmọ-ogun ní Juda nítorí Juda ti kọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀. \v 7 Sikri àti Efraimu alágbára sì pa Maaseiah ọmọ ọba, Aṣrikamu ìjòyè tí ó wà ní ìkáwọ́ ilé ọba, àti Elkana igbákejì ọba. \v 8 Àwọn ọmọ Israẹli sì kó ní ìgbèkùn lára àwọn arákùnrin wọn ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin àti obìnrin wọn sì tún kó ọ̀pọ̀ ìkógun, èyí tí wọn kó padà lọ sí Samaria. \p \v 9 Ṣùgbọ́n wòlíì \nd Olúwa\nd* tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odedi wà níbẹ̀, ó sì jáde lọ láti lọ pàdé ogun nígbà tí ó padà sí Samaria. Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run baba yín bínú sí Juda ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin pa wọ́n ní ìpa oró tí ó de òkè ọ̀run. \v 10 Nísinsin yìí, ẹ̀yin ń pète láti mú ọkùnrin àti obìnrin Juda àti Jerusalẹmu ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú yín, ẹ̀yin kò ha jẹ̀bi \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, àní ẹ̀yin? \v 11 Nísinsin yìí ẹ gbọ́ tèmi! Ẹ rán àwọn ìgbèkùn tí ẹ̀yin ti mú gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà nítorí ìbínú kíkan \nd Olúwa\nd* ń bẹ lórí yín.” \p \v 12 Lẹ́yìn náà, díẹ̀ nínú àwọn olórí ní Efraimu, Asariah ọmọ Jehohanani, Berekiah ọmọ Meṣilemoti, Jehiskiah ọmọ Ṣallumu, àti Amasa ọmọ Hadlai, dìde sí àwọn tí o ti ogun náà bọ̀. \v 13 Wọn si wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá síbí,” “tàbí àwa ti jẹ̀bi níwájú \nd Olúwa\nd*, ṣe ẹ̀yin ń gbèrò láti fi kún ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bi wa ni: nítorí tí ẹ̀bi wa ti tóbi púpọ̀, ìbínú rẹ̀ kíkan sì wà lórí Israẹli.” \p \v 14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ológun tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti ìkógun sílẹ̀ níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo ìjọ ènìyàn. \v 15 Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lú orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbèkùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jeriko, ìlú ọ̀pẹ, wọ́n sì padà sí Samaria. \p \v 16 Ní àkókò ìgbà náà, ọba Ahasi ránṣẹ́ sí ọba Asiria fún ìrànlọ́wọ́. \v 17 Àwọn ará Edomu sì tún padà wá láti kọlu Juda kí wọn sì kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ. \v 18 Nígbà tí àwọn ará Filistini sì ti jagun ní ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n nì àti síhà gúúsù Juda. Wọ́n ṣẹ́gun wọ́n sì gba Beti-Ṣemeṣi, Aijaloni àti Gederoti, àti Soko, Timna, a ri Gimiso, pẹ̀lú ìletò wọn. \v 19 \nd Olúwa\nd* sì rẹ Juda sílẹ̀ nítorí Ahasi ọba Israẹli, nítorí ó sọ Juda di aláìní ìrànlọ́wọ́, ó sì ṣe ìrékọjá gidigidi sí \nd Olúwa\nd*. \v 20 Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́. \v 21 Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé \nd Olúwa\nd* àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́. \p \v 22 Ní àkókò ìpọ́njú rẹ̀ ọba Ahasi sì di aláìṣòótọ́ sí \nd Olúwa\nd*. \v 23 Ó sì rú ẹbọ sí òrìṣà àwọn Damasku, ẹni tí ó ṣẹ́gun wọn, nítorí ó rò wí pé, “Nítorí àwọn òrìṣà àwọn ọba Siria ti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọn kí ó bà lè ràn mí lọ́wọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ni ìparun rẹ̀ àti ti gbogbo Israẹli. \p \v 24 Ahasi sì kó gbogbo ohun èlò láti ilé \nd Olúwa\nd* jọ ó sì kó wọn lọ. Ó sì ti ìlẹ̀kùn ilé \nd Olúwa\nd* ó sì tẹ́ pẹpẹ fún ara rẹ̀ ní gbogbo igun Jerusalẹmu. \v 25 Ní gbogbo ìlú Juda ó sì kọ́ ibi gíga láti sun ẹbọ fún àwọn ọlọ́run mìíràn. Kí ó sì mú \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run àwọn baba wọn bínú. \p \v 26 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Juda àti ti Israẹli. \v 27 Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Jerusalẹmu ṣùgbọ́n wọn kò mú un wá sínú àwọn isà òkú àwọn ọba Israẹli. Hesekiah ọmọ rẹ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \c 29 \s1 Hesekiah sọ ilé \nd Olúwa\nd* di mímọ́ \p \v 1 Hesekiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Abijah ọmọbìnrin Sekariah. \v 2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe. \p \v 3 Ní oṣù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé \nd Olúwa\nd* ó sì tún wọn ṣe. \v 4 Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Lefi, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà-oòrùn. \v 5 Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ baba mi jáde kúrò ní ibi mímọ́. \v 6 Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé \nd Olúwa\nd*, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i. \v 7 Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Israẹli. \v 8 Nítorí náà, ìbínú \nd Olúwa\nd* ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i. \v 9 Ìdí nìyí tí àwọn baba wa ṣe ṣubú nípa idà àti ìdí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa tiwọn kó wọ́n ní ìgbèkùn. \v 10 Nísinsin yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa. \v 11 Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí \nd Olúwa\nd* ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.” \b \li4 \v 12 Nígbà náà àwọn ọmọ Lefi wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́: \b \li1 nínú àwọn ọmọ Kohati, \li2 Mahati ọmọ Amasai: àti Joẹli ọmọ Asariah; \li1 nínú àwọn ọmọ Merari, \li2 Kiṣi ọmọ Abdi àti Asariah ọmọ Jehaleeli; \li1 nínú àwọn ọmọ Gerṣoni, \li2 Joah, ọmọ Simma àti Edeni ọmọ Joah; \li1 \v 13 nínú àwọn ọmọ Elisafani, \li2 Ṣimri àti Jeieli; \li1 nínú àwọn ọmọ Asafu, \li2 Sekariah àti Mattaniah; \li1 \v 14 nínú àwọn ọmọ Hemani, \li2 Jehieli àti Ṣimei; \li1 nínú àwọn ọmọ Jedutuni, \li2 Ṣemaiah àti Usieli. \b \p \v 15 Nígbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ilé \nd Olúwa\nd* mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*. \v 16 Àwọn àlùfáà sì wọ inú ilé \nd Olúwa\nd* lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé \nd Olúwa\nd* gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé \nd Olúwa\nd*. Àwọn ọmọ Lefi sì mú u wọ́n sì gbangba odò Kidironi. \v 17 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro \nd Olúwa\nd*. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn sí i, wọ́n sì ya ilé \nd Olúwa\nd* sí mímọ́ fúnra rẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ín-ní. \p \v 18 Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé \nd Olúwa\nd* mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò. \v 19 A ti pèsè a sì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Ahasi ti sọ di aláìmọ́ nínú àìṣòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsin yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ \nd Olúwa\nd*.” \p \v 20 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hesekiah sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé \nd Olúwa\nd*. \v 21 Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Juda. Ọba pàṣẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, láti ṣe èyí lórí pẹpẹ \nd Olúwa\nd*. \v 22 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ. \v 23 Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. \v 24 Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli. \p \v 25 Ó sì mú àwọn Lefi dúró nínú ilé \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú Kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Gadi aríran ọba àti Natani wòlíì. Èyí ni a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ \nd Olúwa\nd* láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀. \v 26 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ìpè wọn. \p \v 27 Hesekiah sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí \nd Olúwa\nd* bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi ọba Israẹli. \v 28 Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afùnpè sì fọn ìpè, gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán. \p \v 29 Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbọ rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn. \v 30 Pẹ̀lúpẹ̀lú Hesekiah ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi, láti fi ọ̀rọ̀ Dafidi àti ti Asafu aríran, kọrin ìyìn sí \nd Olúwa\nd*: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn. \s1 Ìrúbọ nínú tẹmpili \p \v 31 Nígbà náà ni Hesekiah dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún \nd Olúwa\nd*, ẹ súnmọ́ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá sínú ilé \nd Olúwa\nd*. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá. \p \v 32 Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùn-ún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn, gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ sísun sí \nd Olúwa\nd*. \v 33 Àwọn ohun ìyàsímímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600) màlúù, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. \v 34 Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣẹ́ náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòtítọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́. \v 35 Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun. \p Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ilé \nd Olúwa\nd*. \v 36 Hesekiah sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà. \c 30 \s1 Hesekiah ṣe àsè ìrékọjá \p \v 1 Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé \nd Olúwa\nd* ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli. \v 2 Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì. \v 3 Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu. \v 4 Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn. \v 5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. \p \v 6 Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé, \pm “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria. \v 7 Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí. \v 8 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún \nd Olúwa\nd*, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé. Kí ẹ sì sin \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín. \v 9 Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí \nd Olúwa\nd*, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín, oníyọnu àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.” \p \v 10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ náà kọjá láti ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Efraimu àti Manase títí dé Sebuluni, ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n. \v 11 Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Aṣeri àti Manase àti Sebuluni rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu. \v 12 Ní Juda pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*. \p \v 13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì. \v 14 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi. \p \v 15 Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé \nd Olúwa\nd*. \v 16 Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi. \v 17 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí \nd Olúwa\nd*. \v 18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, \nd Olúwa\nd*, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù, \v 19 tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́ \v 20 \nd Olúwa\nd* sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá. \p \v 21 Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin \nd Olúwa\nd* lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí \nd Olúwa\nd*. \p \v 22 Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere \nd Olúwa\nd*: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run àwọn baba wọn. \p \v 23 Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́. \v 24 Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́. \v 25 Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀. \v 26 Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu. \v 27 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run. \c 31 \p \v 1 Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ jákèjádò Juda àti Benjamini àti ní Efraimu àti Manase. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Israẹli padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn. \s1 Ìdáwó fún ìjọ́sìn \p \v 2 Hesekiah fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Lefi láti tẹ́ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu-ọ̀nà ibùgbé \nd Olúwa\nd*. \v 3 Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin \nd Olúwa\nd*. \v 4 Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin \nd Olúwa\nd*. \v 5 Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá. \v 6 Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì. \v 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje. \v 8 Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. \p \v 9 Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì; \v 10 àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé \nd Olúwa\nd* àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí \nd Olúwa\nd* ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.” \p \v 11 Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé \nd Olúwa\nd*, wọ́n sì ṣe èyí. \v 12 Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀. \v 13 Jehieli, Asasiah, Nahati, Asaheli, Jerimoti, Josabadi, Elieli, Ismakia, Mahati àti Benaiah jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konaniah àti Ṣimei arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Hesekiah àti Asariah olórí ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run. \p \v 14 Kore ọmọ Imina ará Lefi olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ \v 15 Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré. \p \v 16 Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé \nd Olúwa\nd* láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn. \v 17 Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn. \v 18 Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀. \p \v 19 Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi. \p \v 20 Èyí ni Hesekiah ṣe jákèjádò Juda, ó sì ṣe ohun tí ó dára àti tí ó tọ́ àti ohun òtítọ́ níwájú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. \v 21 Nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé ní ti iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Ọlọ́run àti ní ìgbọ́ràn sí òfin àti àwọn àṣẹ. Ó wá Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ó sì ṣe rere. \c 32 \s1 Sennakeribu dẹ́rùba Jerusalẹmu \p \v 1 Lẹ́yìn gbogbo èyí ti Hesekiah ti fi òtítọ́ ṣe, Sennakeribu ọba Asiria wá ó sì gbógun ti Juda. Ó gbógun ti àwọn ìlú ààbò, ó ń ronú láti ṣẹ́gun wọn fún ara rẹ̀. \v 2 Nígbà tí Hesekiah rí i pé Sennakeribu ti wá, àti pé ó fẹ́ láti dá ogun sílẹ̀ lórí Jerusalẹmu, \v 3 Ó gbèrò pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ láti di orísun omi ní ìta ìlú ńlá, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́. \v 4 Ọ̀pọ̀ ogun ọkùnrin péjọ, wọ́n sì dí gbogbo àwọn orísun àti àwọn omi tó ń sàn tí ó ń sàn gba ti ilẹ̀ náà. “Kí ni ó dé tí àwọn ọba Asiria fi wá tí wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ omi?” Wọ́n wí. \v 5 Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta. \p \v 6 Ó yan àwọn ìjòyè ológun sórí àwọn ènìyàn, ó sì pè wọ́n jọ, níwájú rẹ̀ ní ìbámu ní ìlú ńlá ti Dafidi. Ó sì ki wọ́n láyà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: \v 7 “Ẹ jẹ́ alágbára, àti kí ẹ sì ní ìgboyà. Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn nítorí tí ọba Asiria àti ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀, nítorí tí agbára ńlá wà pẹ̀lú wa ju òun lọ. \v 8 Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí. \p \v 9 Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀: \pm \v 10 “Èyí ni ohun tí Sennakeribu ọba Asiria wí, ‘Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbógun sí?’ \v 11 Nígbà tí Hesekiah wí pé, ‘\nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria,’ ó ń ṣì yín tọ́ ṣọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ. \v 12 Ṣé Hesekiah fúnra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lórí rẹ̀’? \pm \v 13 “Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn baba mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi? \v 14 Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi? \v 15 Nísinsin yìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ó tàn yín àti ṣì yín tọ́ ṣọ́nà báyìí. Ẹ má ṣe gbà á gbọ́, nítorí tí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn baba mi, mélòó mélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!” \p \v 16 Àwọn ìjòyè Sennakeribu sọ̀rọ̀ síwájú sí i ní ìlòdì sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àti sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Hesekiah. \v 17 Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí: “Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Hesekiah kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi.” \v 18 Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Heberu sí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ fún wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà. \v 19 Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Jerusalẹmu bí wọ́n ti ṣe nípa àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn mìíràn ti àgbáyé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn. \p \v 20 Ọba Hesekiah àti wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sọkún jáde nínú àdúrà sí ọ̀run nípa èyí. \v 21 \nd Olúwa\nd* sì ran angẹli tí ó pa gbogbo àwọn ọmọ-ogun àti àwọn adarí àti àwọn ìjòyè tí ó wà nínú àgọ́ ọba Asiria run. Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí ilẹ̀ rẹ̀ ní ìtìjú. Nígbà tí ó sì lọ sínú ilé ọlọ́run rẹ̀, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà. \p \v 22 Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* yọ Hesekiah àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ Sennakeribu ọba Asiria àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà. \v 23 Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún \nd Olúwa\nd* àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà. \s1 Ìgbéraga, àṣeyọrí àti ikú Hesekiah \p \v 24 Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí \nd Olúwa\nd* tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu. \v 25 Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú \nd Olúwa\nd* wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu. \v 26 Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú \nd Olúwa\nd* kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah. \p \v 27 Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye. \v 28 Ó kọ́ àwọn ilé pẹ̀lú láti tọ́jú àwọn ọkà àwọn tí wọ́n ka, ọtí tuntun àti òróró; ó sì ṣe àwọn àtíbàbà fún oríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn àti àwọn àṣémọ́ fun àwọn ọ̀wọ̀ ẹran. \v 29 Ó kọ́ àwọn ìletò, ó sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, nítorí tí Ọlọ́run ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá. \p \v 30 Hesekiah ni ó dí ojú ìṣúra apá òkè ti orísun Gihoni. Ó sì gbe gba ìsàlẹ̀ sí ìhà ìwọ oòrùn ìlú ńlá ti Dafidi. Ó ṣe àṣeyọrí rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. \v 31 Ṣùgbọ́n nígbà tí a rán àwọn oníṣẹ́ ọba wá láti Babeli láti bi í lérè nípa àmì ìyanu tí ó ṣẹlẹ̀ nì, Ọlọ́run fi sílẹ̀ láti dán an wò àti láti mọ gbogbo nǹkan tí ó wà lọ́kàn rẹ̀. \p \v 32 Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Hesekiah àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Isaiah ọmọ Amosi nínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli \v 33 Hesekiah sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dafidi wà. Gbogbo Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Manase ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \c 33 \s1 Manase ọba Juda \p \v 1 Manase jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta. \v 2 Ó sì ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd*. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀-èdè tí \nd Olúwa\nd* ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli rìn. \v 3 Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Baali ó sì ṣe àwọn ère Aṣerah. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n. \v 4 Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé \nd Olúwa\nd* ní èyí tí \nd Olúwa\nd* ti wí pé, “Orúkọ mi yóò wà ní Jerusalẹmu títí láé.” \v 5 Nínú ààfin méjèèje ti ilé \nd Olúwa\nd*, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run \v 6 Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú \nd Olúwa\nd* láti mú un bínú. \p \v 7 Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé \nd Olúwa\nd*, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé \nd Olúwa\nd* yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. \v 8 Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.” \v 9 Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí \nd Olúwa\nd* ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli. \p \v 10 \nd Olúwa\nd* bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i. \v 11 Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli. \v 12 Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀. \v 13 Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú \nd Olúwa\nd* dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé \nd Olúwa\nd* ni Ọlọ́run. \p \v 14 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí, ó mọ odi kan lẹ́yìn ìlú Dafidi, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, àní ní àtiwọ ẹnu ibodè ẹja, ó sì yí orí òkè Ofeli ká; ó sì mọ ọ́n ga sókè gidigidi, ó sì fi balógun sínú gbogbo ìlú olódi Juda wọ̀n-ọn-nì. \p \v 15 Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjèjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé \nd Olúwa\nd* àti ní Jerusalẹmu; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú. \v 16 Nígbà náà ni ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ-ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Juda láti sin \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli. \v 17 Àwọn ènìyàn, ko tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wọn nìkan. \p \v 18 Àwọn iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Manase pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i ní orúkọ \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. \v 19 Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìṣòótọ́, àti àwọn òpó níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìrántí àwọn aríran. \v 20 Manase sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Amoni ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \s1 Amoni ọba Juda \p \v 21 Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. \v 22 Ó ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. Amoni rú ẹbọ sí gbogbo àwọn òrìṣà tí Manase baba rẹ̀ ti ṣe, ó sì sìn wọ́n. \v 23 Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba rẹ̀ Manase. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd*: ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Amoni sì ń pọ̀ sì í. \p \v 24 Àwọn oníṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ sí i. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. \v 25 Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì mú Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \c 34 \s1 Josiah gbógun ti ìwà ìbọ̀rìṣà \p \v 1 Josiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. \v 2 Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú \nd Olúwa\nd*, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dafidi, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì. \p \v 3 Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ojú Ọlọ́run baba Dafidi. Ní ọdún kejìlá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ Juda àti Jerusalẹmu mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah, àti ère yíyá àti ère dídà. \v 4 Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Baali ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú, àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lúúlúú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí isà òkú àti àwọn tí ó ń rú ẹbọ sí wọn. \v 5 Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́. \v 6 Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri. \v 7 Ó sì wó pẹpẹ àti ère Aṣerah lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Israẹli. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jerusalẹmu. \p \v 8 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé \nd Olúwa\nd*, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ṣe. \p \v 9 Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, ó sì fún un ní owó náà tí ó mú wá sí inú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Lefi ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Manase Efraimu àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù Israẹli àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Juda àti Benjamini wọ́n sì padà sí Jerusalẹmu. \v 10 Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé \nd Olúwa\nd*. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé \nd Olúwa\nd*. \v 11 Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn oníṣọ̀nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Juda ti gbà láti túnṣe. \p \v 12 Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́, láti darí wọn ní Jahati àti Obadiah, àwọn ọmọ Lefi láti Merari, àti Sekariah àti Meṣullamu, sọ̀kalẹ̀ láti Kohati àwọn ọmọ Lefi gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin. \v 13 Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà. \s1 A rí ìwé òfin \p \v 14 Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé \nd Olúwa\nd*, Hilkiah àlùfáà sì rí ìwé òfin \nd Olúwa\nd* tí a ti fi fún un láti ọwọ́ Mose. \v 15 Hilkiah sì wí fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwé òfin nínú ilé \nd Olúwa\nd*.” Ó sì fi fún Ṣafani. \p \v 16 Nígbà náà Ṣafani sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́. \v 17 Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé \nd Olúwa\nd* wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́.” \v 18 Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hilkiah àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣafani sì kà níwájú ọba. \p \v 19 Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. \v 20 Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. \v 21 “Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd* fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú \nd Olúwa\nd* tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.” \p \v 22 Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì. \p \v 23 Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, \v 24 ‘Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.” \v 25 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’ \v 26 Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*, ‘Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́. \v 27 Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró, ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú \nd Olúwa\nd* nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibí yìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni \nd Olúwa\nd* wí. \v 28 Nísinsin yìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibí yìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ” \p Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba. \p \v 29 Nígbà náà ni ọba sì pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda jọ àti Jerusalẹmu. \v 30 Ó gòkè lọ sí ilé \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèké sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé \nd Olúwa\nd*. \v 31 Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú \nd Olúwa\nd*, láti tẹ̀lé \nd Olúwa\nd* àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé yìí. \p \v 32 Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jerusalẹmu àti Benjamini dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run baba ńlá wọn. \p \v 33 Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn. \c 35 \s1 Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá \p \v 1 Síwájú sí i, Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí \nd Olúwa\nd* ní Jerusalẹmu, Ọ̀dọ́-àgùntàn àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. \v 2 Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé \nd Olúwa\nd*. \v 3 Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún \nd Olúwa\nd* pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé \nd Olúwa\nd* tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli. \v 4 Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dafidi ọba Israẹli àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Solomoni. \p \v 5 “Dúró ní ibi mímọ́ pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Lefi fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpín àwọn ìdílé àwọn ẹgbẹ́ ará ìlú, àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀. \v 6 Ẹ pa ẹran àjọ ìrékọjá náà, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì pèsè ẹran fún àwọn ẹgbẹ́ arákùnrin yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí \nd Olúwa\nd* paláṣẹ láti ọwọ́ Mose.” \p \v 7 Josiah sì pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó dùbúlẹ̀ tí ó wà níbẹ̀ iye rẹ̀ jẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọmọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ìrékọjá, àti pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọ màlúù, gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ohun ìní láti ọ̀dọ̀ ọba. \p \v 8 Àwọn ìjòyè rẹ̀ fi tinútinú ta àwọn ènìyàn náà ní ọrẹ àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Hilkiah, Sekariah àti Jehieli, àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run, fún àwọn àlùfáà ní ẹgbẹ̀tàlá (2,600) ẹbọ àjọ ìrékọjá àti ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹran ọ̀sìn. \v 9 Àti pẹ̀lú Konaniah àti pẹ̀lú Ṣemaiah àti Netaneli, àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti Haṣabiah, Jeieli àti Josabadi olórí àwọn ọmọ Lefi, ó sì pèsè ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ẹbọ ìrékọjá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) orí ẹran ọ̀sìn fún àwọn ọmọ Lefi. \p \v 10 Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ. \v 11 Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Lefi sì bọ ẹranko. \v 12 Wọ́n sì ya àwọn ẹbọ sísun sí apá kan láti fi wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ìdílé àwọn ènìyàn láti rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd*. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé Mose. Wọ́n sì ṣe bákan náà pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn. \v 13 Wọ́n sì fi sun àjọ ìrékọjá lórí iná gẹ́gẹ́ bí ìlànà, wọ́n sì bọ ẹbọ mímọ́ nínú ìkòkò, nínú ọpọ́n àti nínú agbada, wọ́n sì pín wọn kíákíá fún gbogbo àwọn ènìyàn. \v 14 Lẹ́yìn èyí, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn àlùfáà nítorí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Aaroni, ni wọ́n rú ẹbọ sísun àti ọ̀rá títí di àṣálẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì múra sílẹ̀ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ Aaroni àlùfáà. \p \v 15 Àwọn akọrin, àwọn ọmọ Asafu, ni wọ́n wà ní ipò wọn tí a sì paláṣẹ fún wọn láti ọwọ́ Dafidi, Asafu, Hemani àti Jedutuni àwọn aríran ọba àti àwọn olùṣọ́nà ní olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà kò gbọdọ̀ fi ojú ọ̀nà wọn sílẹ̀, nítorí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ lefi ti múra sílẹ̀ fún wọn. \p \v 16 Bẹ́ẹ̀ ni àsìkò náà gbogbo àwọn ìsìn \nd Olúwa\nd* ni wọ́n gbé jáde fún iṣẹ́ ìrántí àjọ ìrékọjá àti láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ọba Josiah ti pa á láṣẹ. \v 17 Àwọn ọmọ Israẹli tí ó gbé kalẹ̀ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá ní àkókò náà àti àjọ àkàrà àìwú fún ọjọ́ méje. \v 18 Àjọ ìrékọjá náà kò sì tí ì sí èyí tí ó dàbí i rẹ̀ ní Israẹli títí dé ọjọ́ wòlíì Samuẹli, kò sì sí ọ̀kan lára àwọn ọba Israẹli tí ó pa irú àjọ ìrékọjá bẹ́ẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Josiah ti ṣe, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo àwọn Juda àti Israẹli tí ó wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu. \v 19 Àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah. \s1 Ikú Josiah \p \v 20 Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà. \v 21 Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.” \p \v 22 Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido. \p \v 23 Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.” \v 24 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Juda àti gbogbo Jerusalẹmu sì ṣọ̀fọ̀ Josiah. \p \v 25 Jeremiah sì pohùnréré ẹkún fún Josiah, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Josiah nínú orin ẹkún wọn ní Israẹli títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jerusalẹmu, a sì kọ ọ́ sínú àwọn orin ẹkún. \p \v 26 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Josiah àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínú ìwé òfin \nd Olúwa\nd*. \v 27 Gbogbo iṣẹ́ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. \c 36 \nb \v 1 Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah wọn sì fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu ni ipò baba rẹ̀. \s1 Jehoahasi ọba Juda \p \v 2 Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. \v 3 Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan. \v 4 Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti. \s1 Jehoiakimu ọba Juda \p \v 5 Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀. \v 6 Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli. \v 7 Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé \nd Olúwa\nd* lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli. \p \v 8 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \s1 Jehoiakini ọba Juda \p \v 9 Jehoiakini sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd*. \v 10 Ní àkókò òjò, ọba Nebukadnessari ránṣẹ́ sí i ó sì mú un wá sí Babeli, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé \nd Olúwa\nd*, ó sì mú arákùnrin Jehoiakini, Sedekiah, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu. \s1 Sedekiah ọba Juda \p \v 11 Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. \v 12 Ó sì ṣe búburú ní ojú \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*. \v 13 Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli. \v 14 Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé \nd Olúwa\nd* di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu. \s1 Ìṣubú Jerusalẹmu \p \v 15 \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀. \v 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú \nd Olúwa\nd* fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe. \v 17 Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́. \v 18 Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé \nd Olúwa\nd* àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀. \v 19 Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́. \p \v 20 Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára. \v 21 Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tí a sọ láti ẹnu Jeremiah. \p \v 22 Ní ọdún kìn-ín-ní Kirusi ọba Persia, kí ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tí a tẹnu Jeremiah sọ bá à le ṣẹ pé, \nd Olúwa\nd* run ẹ̀mí Kirusi ọba Persia láti ṣe ìkéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì kọ ọ́ sínú ìwé pẹ̀lú. \pmo \v 23 “Èyí ni ohun tí Kirusi ọba Persia sọ wí pé: \pm “ ‘\nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mí ní gbogbo ìjọba ayé yìí, ó sì ti yàn mí láti kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* fún òun ní Jerusalẹmu ti Juda. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàrín yín le gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀; kí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.’ ”