\id 1CH - Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017 \ide UTF-8 \h 1 Kronika \toc1 Ìwé Kronika Kìn-ín-ní \toc2 1 Kronika \toc3 1Ki \mt1 Ìwé Kronika Kìn-ín-ní \c 1 \s1 Ìran Adamu títí de Abrahamu \s2 Títí dé ọmọkùnrin Noa \li1 \v 1 Adamu, Seti, Enoṣi, \li1 \v 2 Kenani, Mahalaleli, Jaredi, \li1 \v 3 Enoku, Metusela, Lameki, \li1 Noa. \b \li4 \v 4 Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti. \s2 Àwọn Ọmọ Jafeti \li1 \v 5 Àwọn ọmọ Jafeti ni: \li2 Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi. \li1 \v 6 Àwọn ọmọ Gomeri ni: \li2 Aṣkenasi, Rifati àti Togarma. \li1 \v 7 Àwọn ọmọ Jafani ni: \li2 Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. \s2 Àwọn ọmọ Hamu \li1 \v 8 Àwọn ọmọ Hamu ni: \li2 Kuṣi, Ejibiti, Puti, àti Kenaani. \li1 \v 9 Àwọn ọmọ Kuṣi ni: \li2 Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. \li1 Àwọn ọmọ Raama: \li2 Ṣeba àti Dedani. \li1 \v 10 Kuṣi sì bí Nimrodu \li2 ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. \li1 \v 11 Ejibiti sì bí \li2 Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, \v 12 Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu. \li1 \v 13 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, \li2 àti Heti, \v 14 àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, \v 15 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, \v 16 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. \s2 Àwọn ará Ṣemu. \li1 \v 17 Àwọn ọmọ Ṣemu ni: \li2 Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. \li1 Àwọn ọmọ Aramu: \li2 Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki. \li1 \v 18 Arfakṣadi sì bí Ṣela, \li2 Ṣela sì bí Eberi. \li1 \v 19 Eberi sì bí ọmọ méjì: \li2 ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani. \li1 \v 20 Joktani sì bí \li2 Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. \v 21 Hadoramu, Usali, Dikla, \v 22 Ebali, Abimaeli, Ṣeba. \v 23 Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani. \b \li1 \v 24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela, \li1 \v 25 Eberi, Pelegi. Reu, \li1 \v 26 Serugu, Nahori, Tẹra, \li1 \v 27 àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu). \s1 Ìdílé Abrahamu \li4 \v 28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli. \s2 Àwọn ọmọ Hagari \li1 \v 29 Èyí ni àwọn ọmọ náà: \li2 Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu, \v 30 Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, \v 31 Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. \li4 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli. \s2 Àwọn ọmọ Ketura \li1 \v 32 Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu: \li2 Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua. \li1 Àwọn ọmọ Jokṣani: \li2 Ṣeba àti Dedani. \li1 \v 33 Àwọn ọmọ Midiani: \li2 Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. \li4 Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura. \s2 Àwọn Ìran Sara \li4 \v 34 Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki. \li1 Àwọn ọmọ Isaaki: \li2 Esau àti Israẹli. \s1 Àwọn ọmọ Esau \li1 \v 35 Àwọn ọmọ Esau: \li2 Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. \li1 \v 36 Àwọn ọmọ Elifasi: \li2 Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi; \li2 láti Timna: Amaleki. \li1 \v 37 Àwọn ọmọ Reueli: \li2 Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. \s2 Àwọn ènìyàn Seiri ní Edomu \li1 \v 38 Àwọn ọmọ Seiri: \li2 Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani. \li1 \v 39 Àwọn ọmọ Lotani: \li2 Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani. \li1 \v 40 Àwọn ọmọ Ṣobali: \li2 Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu. \li1 Àwọn ọmọ Sibeoni: \li2 Aiah àti Ana. \li1 \v 41 Àwọn ọmọ Ana: \li2 Diṣoni. \li1 Àwọn ọmọ Diṣoni: \li2 Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani. \li1 \v 42 Àwọn ọmọ Eseri: \li2 Bilhani, Saafani àti Akani. \li1 Àwọn ọmọ Diṣani: \li2 Usi àti Arani. \s2 Àwọn alákòóso Edomu \li4 \v 43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli: \li1 Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba. \li1 \v 44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \li1 \v 45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \li1 \v 46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti. \li1 \v 47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \li1 \v 48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \li1 \v 49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \li1 \v 50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. \v 51 Hadadi sì kú pẹ̀lú. \b \li4 Àwọn baálẹ̀ Edomu ni: \li1 baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti \v 52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. \v 53 Baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, \v 54 Magdieli àti Iramu. \li4 Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu. \c 2 \s1 Àwọn ọmọ Israẹli \li4 \v 1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, \v 2 Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri. \s1 Juda \s2 Àwọn ọmọ Hesroni \li1 \v 3 Àwọn ọmọ Juda: \li2 Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. \li2 Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú \nd Olúwa\nd*, bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* sì pa á. \li2 \v 4 Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀. \b \li1 \v 5 Àwọn ọmọ Peresi: \li2 Hesroni àti Hamulu. \li1 \v 6 Àwọn ọmọ Sera: \li2 Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún. \li1 \v 7 Àwọn ọmọ Karmi: \li2 Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀. \li1 \v 8 Àwọn ọmọ Etani: \li2 Asariah. \li1 \v 9 Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: \li2 Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu. \s2 Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni \li1 \v 10 Ramu sì ni baba Amminadabu, \li1 àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda. \li1 \v 11 Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, \li1 Salmoni ni baba Boasi, \li1 \v 12 Boasi baba Obedi \li1 àti Obedi baba Jese. \b \li1 \v 13 Jese sì ni baba \li2 Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì sì ni Abinadabu, \li2 ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣimea, \v 14 ẹlẹ́ẹ̀kẹrin Netaneli, \li2 ẹlẹ́ẹ̀karùnún Raddai, \v 15 ẹlẹ́ẹ̀kẹfà Osemu \li2 àti ẹlẹ́ẹ̀keje Dafidi. \li2 \v 16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili. \li3 Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli. \li3 \v 17 Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli. \s2 Kalebu ọmọ Hesroni \li1 \v 18 Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀: \li2 Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni. \li1 \v 19 Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un. \li2 \v 20 Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli. \b \li1 \v 21 Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu. \li2 \v 22 Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi. \li2 \v 23 (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) \li4 Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi. \li1 \v 24 Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un. \s2 Jerahmeeli ọmọ Hesroni \li1 \v 25 Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni: \li2 Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. \v 26 Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu. \li1 \v 27 Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli: \li2 Maasi, Jamini àti Ekeri. \li1 \v 28 Àwọn ọmọ Onamu: \li2 Ṣammai àti Jada. \li1 Àwọn ọmọ Ṣammai: \li2 Nadabu àti Abiṣuri. \v 29 Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi. \li1 \v 30 Àwọn ọmọ Nadabu \li2 Seledi àti Appaimu. Seledi sì kú láìsí ọmọ. \li1 \v 31 Àwọn ọmọ Appaimu: \li2 Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai. \li1 \v 32 Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai: \li2 Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ. \li1 \v 33 Àwọn ọmọ Jonatani: \li2 Peleti àti Sasa. \li4 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli. \b \li1 \v 34 Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní. \li2 Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. \v 35 Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai. \li1 \v 36 Attai sì jẹ́ baba fún Natani, \li1 Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi, \li1 \v 37 Sabadi ni baba Eflali, \li1 Eflali jẹ́ baba Obedi, \li1 \v 38 Obedi sì ni baba Jehu, \li1 Jehu ni baba Asariah, \li1 \v 39 Asariah sì ni baba Helesi, \li1 Helesi ni baba Eleasa, \li1 \v 40 Eleasa ni baba Sismai, \li1 Sismai ni baba Ṣallumu, \li1 \v 41 Ṣallumu sì ni baba Jekamiah, \li1 Jekamiah sì ni baba Eliṣama. \s2 Ìdílé Kalebu \li1 \v 42 Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: \li2 Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, \li2 àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni. \li1 \v 43 Àwọn ọmọ Hebroni: \li2 Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema. \li1 \v 44 Ṣema ni baba Rahamu, \li2 Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu. \li1 Rekemu sì ni baba Ṣammai. \li1 \v 45 Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni, \li2 Maoni sì ni baba Beti-Suri. \li1 \v 46 Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá \li2 Harani, Mosa àti Gasesi, \li2 Harani sì ni baba Gasesi. \li1 \v 47 Àwọn ọmọ Jahdai: \li2 Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafu. \li1 \v 48 Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá \li2 Seberi àti Tirhana. \li2 \v 49 Ó sì bí Ṣaafu baba Madmana, \li2 Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah, \li1 ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa. \li4 \v 50 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. \b \li1 Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: \li2 Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. \v 51 Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi. \li1 \v 52 Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni: \li2 Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. \v 53 Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá. \li1 \v 54 Àwọn ọmọ Salma: \li2 Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, \v 55 àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu. \c 3 \s2 Àwọn ọmọ Dafidi \li4 \v 1 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni. \b \li1 Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; \li1 èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli; \li1 \v 2 ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; \li1 ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; \li1 \v 3 ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; \li1 àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀. \b \li4 \v 4 Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. \b \b \li4 Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. \v 5 Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: \b \li1 Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli. \li1 \v 6 Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, \v 7 Noga, Nefegi, Jafia, \v 8 Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n. \b \li4 \v 9 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn. \s2 Àwọn ọba Juda \li1 \v 10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu, \li1 Abijah ọmọ rẹ̀, \li1 Asa ọmọ rẹ̀, \li1 Jehoṣafati ọmọ rẹ̀, \li1 \v 11 Jehoramu ọmọ rẹ̀, \li1 Ahasiah ọmọ rẹ̀, \li1 Joaṣi ọmọ rẹ̀, \li1 \v 12 Amasiah ọmọ rẹ̀, \li1 Asariah ọmọ rẹ̀, \li1 Jotamu ọmọ rẹ̀, \li1 \v 13 Ahasi ọmọ rẹ̀, \li1 Hesekiah ọmọ rẹ̀, \li1 Manase ọmọ rẹ̀, \li1 \v 14 Amoni ọmọ rẹ̀, \li1 Josiah ọmọ rẹ̀. \li1 \v 15 Àwọn ọmọ Josiah: \li2 àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, \li2 èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, \li2 ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, \li2 ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu. \li1 \v 16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu: \li2 Jekoniah ọmọ rẹ̀, \li2 àti Sedekiah. \s2 Ìdílé ọba lẹ́yìn ìgbèkùn \li1 \v 17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn: \li2 Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, \v 18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah. \li1 \v 19 Àwọn ọmọ Pedaiah: \li2 Serubbabeli àti Ṣimei. \li1 Àwọn ọmọ Serubbabeli: \li2 Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn. \v 20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi. \li1 \v 21 Àwọn ọmọ Hananiah: \li2 Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Obadiah àti ti Ṣekaniah. \li1 \v 22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah: \li2 Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn. \li1 \v 23 Àwọn ọmọ Neariah: \li2 Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn. \li1 \v 24 Àwọn ọmọ Elioenai: \li2 Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn. \c 4 \s2 Ìran Juda \li1 \v 1 Àwọn ọmọ Juda: \li2 Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali. \li1 \v 2 Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati. \li1 \v 3 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu: \li2 Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi \v 4 Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa. \li1 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu. \li1 \v 5 Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara. \li1 \v 6 Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara. \li1 \v 7 Àwọn ọmọ Hela: \li2 Sereti Sohari, Etani, \v 8 àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu. \b \p \v 9 Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” \v 10 Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún mi, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀. \b \li1 \v 11 Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. \v 12 Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka. \b \li1 \v 13 Àwọn ọmọ Kenasi: \li2 Otnieli àti Seraiah. \li1 Àwọn ọmọ Otnieli: \li2 Hatati àti Meonotai. \v 14 Meonotai sì ni baba Ofira. \li1 Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, \li2 baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n. \li1 \v 15 Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne: \li2 Iru, Ela, àti Naamu. \li1 Àwọn ọmọ Ela: \li2 Kenasi. \li1 \v 16 Àwọn ọmọ Jehaleeli: \li2 Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli. \li1 \v 17 Àwọn ọmọ Esra: \li2 Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni. \li1 Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa. \li1 \v 18 Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́. \li1 \v 19 Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu, \li2 baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati. \li1 \v 20 Àwọn ọmọ Ṣimoni: \li2 Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni. \li1 Àwọn ọmọ Iṣi: \li2 Soheti àti Beni-Soheti. \li1 \v 21 Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda: \li2 Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea. \li2 \v 22 Jokimu, ọkùnrin Koseba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́.) \v 23 Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba. \s1 Simeoni \li1 \v 24 Àwọn ọmọ Simeoni: \li2 Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu; \li2 \v 25 Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀. \li1 \v 26 Àwọn ọmọ Miṣima: \li2 Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀. \b \p \v 27 Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìndínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. \v 28 Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, \v 29 àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, \v 30 Betueli, Horma, Siklagi, \v 31 Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, \v 32 agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, \v 33 àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn. \b \li4 Àti ìtàn ìdílé wọ́n. \b \li1 \v 34 Meṣobabu àti Jamleki, \li1 Josa ọmọ Amasiah, \v 35 Joẹli, \li1 Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli, \li1 \v 36 àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah, \li1 Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah, \li1 \v 37 àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah. \b \li4 \v 38 Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn. \b \p Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, \v 39 wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn. \v 40 Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. \p \v 41 Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. \v 42 Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. \v 43 Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí. \c 5 \s1 Rubeni \li4 \v 1 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. \v 2 Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), \v 3 àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni: \b \li2 Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi. \li1 \v 4 Àwọn ọmọ Joẹli: \li2 Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, \li2 Ṣimei ọmọ rẹ̀. \v 5 Mika ọmọ rẹ̀, \li2 Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀. \li2 \v 6 Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́. \li1 \v 7 Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn: \li2 Jeieli àti Sekariah ni olórí, \v 8 àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli. \b \p Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. \v 9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi. \p \v 10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi. \s1 Ìdílé Gadi \li4 \v 11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka: \b \li1 \v 12 Joẹli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ Janai, àti Ṣafati ni Baṣani. \li1 \v 13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní: \li2 Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje. \li2 \v 14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi. \li2 \v 15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn. \b \p \v 16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn. \p \v 17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli. \b \p \v 18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì (47,760) ènìyàn, tí ó jáde lọ sí ogún náà. \v 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. \v 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. \v 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000) àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún (250,000), àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì (2,000), àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000). \v 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn. \s1 Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase \p \v 23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni. \p \v 24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. \v 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. \v 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí. \c 6 \s1 Lefi \li1 \v 1 Àwọn ọmọ Lefi: \li2 Gerṣoni, Kohati àti Merari. \li1 \v 2 Àwọn ọmọ Kohati: \li2 Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli. \li1 \v 3 Àwọn ọmọ Amramu: \li2 Aaroni, Mose àti Miriamu. \li1 Àwọn ọmọkùnrin Aaroni: \li2 Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. \li2 \v 4 Eleasari jẹ́ baba Finehasi, \li2 Finehasi baba Abiṣua \li2 \v 5 Abiṣua baba Bukki, \li2 Bukki baba Ussi, \li2 \v 6 Ussi baba Serahiah, \li2 Serahiah baba Meraioti, \li2 \v 7 Meraioti baba Amariah, \li2 Amariah baba Ahitubu \li2 \v 8 Ahitubu baba Sadoku, \li2 Sadoku baba Ahimasi, \li2 \v 9 Ahimasi baba Asariah, \li2 Asariah baba Johanani, \li2 \v 10 Johanani baba Asariah. \li2 (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé \nd Olúwa\nd* tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu). \li2 \v 11 Asariah baba Amariah \li2 Amariah baba Ahitubu \li2 \v 12 Ahitubu baba Sadoku. \li2 Sadoku baba Ṣallumu, \li2 \v 13 Ṣallumu baba Hilkiah, \li2 Hilkiah baba Asariah, \li2 \v 14 Asariah baba Seraiah, \li2 pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki. \li2 \v 15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí \nd Olúwa\nd* lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari. \b \li1 \v 16 Àwọn ọmọ Lefi: \li2 Gerṣoni, Kohati àti Merari. \li1 \v 17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: \li2 Libni àti Ṣimei. \li1 \v 18 Àwọn ọmọ Kohati: \li2 Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. \li1 \v 19 Àwọn ọmọ Merari: \li2 Mahili àti Muṣi. \b \li4 Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn. \li1 \v 20 Ti Gerṣoni: \li2 Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati. \li2 Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀, \v 21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀, \li2 Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀ \li2 àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀. \li1 \v 22 Àwọn ìran ọmọ Kohati: \li2 Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀, \li2 Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. \v 23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀, \li2 Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. \li2 \v 24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀, \li2 Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀. \li1 \v 25 Àwọn ìran ọmọ Elkana: \li2 Amasai, Ahimoti \li2 \v 26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀ \li2 Nahati ọmọ rẹ̀, \v 27 Eliabu ọmọ rẹ̀, \li2 Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀ \li2 àti Samuẹli ọmọ rẹ̀. \li1 \v 28 Àwọn ọmọ Samuẹli: \li2 Joẹli àkọ́bí \li2 àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì. \li1 \v 29 Àwọn ìran ọmọ Merari: \li2 Mahili, Libni ọmọ rẹ̀. \li2 Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀. \li2 \v 30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀ \li2 àti Asaiah ọmọ rẹ̀. \s2 Ilé ti a kọ́ fún àwọn Olórin \p \v 31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé \nd Olúwa\nd* lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. \v 32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn. \b \li4 \v 33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. \b \li1 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: \li2 Hemani olùkọrin, \li2 ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli, \li2 \v 34 ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, \li2 ọmọ Elieli, ọmọ Toha, \li2 \v 35 ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, \li2 ọmọ Mahati, ọmọ Amasai, \li2 \v 36 ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, \li2 ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah, \li2 \v 37 ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, \li2 ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, \li2 \v 38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati, \li2 ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli; \li1 \v 39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀: \li2 Asafu ọmọ Berekiah, ọmọ Ṣimea, \li2 \v 40 ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, \li2 ọmọ Malkiah \v 41 ọmọ Etini, \li2 ọmọ Sera, ọmọ Adaiah, \li2 \v 42 ọmọ Etani, ọmọ Simma, \li2 ọmọ Ṣimei, \v 43 ọmọ Jahati, \li2 ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi; \li1 \v 44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀: \li2 Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, \li2 ọmọ Malluki, \v 45 ọmọ Haṣabiah, \li2 ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah, \li2 \v 46 ọmọ Amisi, ọmọ Bani, \li2 ọmọ Ṣemeri, \v 47 ọmọ Mahili, \li2 ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, \li2 ọmọ Lefi. \b \p \v 48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run. \v 49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ. \b \li1 \v 50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni: \li2 Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, \li2 Abiṣua ọmọ rẹ̀, \v 51 Bukki ọmọ rẹ̀, \li2 Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀, \li2 \v 52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, \li2 Ahitubu ọmọ rẹ̀, \v 53 Sadoku ọmọ rẹ̀ \li2 àti Ahimasi ọmọ rẹ̀. \b \li4 \v 54 Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn). \li1 \v 55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. \v 56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne. \v 57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa, \v 58 Hileni, Debiri, \v 59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. \li1 \v 60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \li4 Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀. \b \li1 \v 61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase. \li1 \v 62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani. \li1 \v 63 Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni. \b \li4 \v 64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \b \li1 \v 65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún. \b \li4 \v 66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn. \li1 \v 67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri \v 68 Jokimeamu, Beti-Horoni. \v 69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \li1 \v 70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati. \b \li4 \v 71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí. \li1 Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn. \li1 \v 72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati \v 73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \li1 \v 74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni, \v 75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \li1 \v 76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. \b \li4 \v 77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí. \li1 Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. \li1 \v 78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa, \v 79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. \li1 \v 80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu, \v 81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. \c 7 \s1 Isakari \li1 \v 1 Àwọn ọmọ Isakari: \li2 Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀. \li1 \v 2 Àwọn ọmọ Tola: \li2 Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀ta (22,600). \li1 \v 3 Àwọn ọmọ, Ussi: \li2 Israhiah. \li1 Àwọn ọmọ Israhiah: \li2 Mikaeli, Obadiah, Joẹli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè. \v 4 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (36,000) tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó. \li4 \v 5 Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádọ́rin (87,000) ni gbogbo rẹ̀. \s1 Benjamini \li1 \v 6 Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini: \li2 Bela, Bekeri àti Jediaeli. \li1 \v 7 Àwọn ọmọ Bela: \li2 Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (22,034) ènìyàn. \li1 \v 8 Àwọn ọmọ Bekeri: \li2 Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri. \v 9 Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó lé nígba (20,200) ọkùnrin alágbára. \li1 \v 10 Ọmọ Jediaeli: \li2 Bilhani. \li1 Àwọn ọmọ Bilhani: \li2 Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari. \v 11 Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba (17,200) akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun. \li1 \v 12 Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri. \s1 Naftali \li1 \v 13 Àwọn ọmọ Naftali: \li2 Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha. \s1 Manase \li1 \v 14 Àwọn ìran ọmọ Manase: \li2 Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi. \v 15 Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo. \v 16 Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu. \li1 \v 17 Ọmọ Ulamu: \li2 Bedani. \li1 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase. \li1 \v 18 Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila. \li1 \v 19 Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́: \li2 Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu. \s1 Efraimu \li1 \v 20 Àwọn ìran ọmọ Efraimu: \li2 Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, \li2 Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. \li2 Tahati ọmọ rẹ̀ \v 21 Sabadi ọmọ, rẹ̀, \li2 àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. \li2 Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn \v 22 Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú. \v 23 Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà. \v 24 Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú. \li2 \v 25 Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, \li2 Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀, \li2 \v 26 Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, \li2 Eliṣama ọmọ rẹ̀, \v 27 Nuni ọmọ rẹ̀ \li2 àti Joṣua ọmọ rẹ̀. \li4 \v 28 Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò. \v 29 Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí. \s1 Aṣeri \li1 \v 30 Àwọn ọmọ Aṣeri: \li2 Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera. \li1 \v 31 Àwọn ọmọ Beriah: \li2 Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti. \li1 \v 32 Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua. \li1 \v 33 Àwọn ọmọ Jafileti: \li2 Pasaki, Bimhali àti Asifati. \li4 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti. \li1 \v 34 Àwọn ọmọ Ṣomeri: \li2 Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu. \li1 \v 35 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu \li2 Sofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali. \li1 \v 36 Àwọn ọmọ Sofahi: \li2 Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra. \v 37 Beseri, Hodi, Ṣamma, Ṣilisa, Itrani àti Bera. \li1 \v 38 Àwọn ọmọ Jeteri: \li2 Jefunne, Pisifa àti Ara. \li1 \v 39 Àwọn ọmọ Ulla: \li2 Arah, Hannieli àti Resia. \li4 \v 40 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin. \c 8 \s1 Ìtàn Ìdílé láti Ọ̀dọ̀ Baba Ńlá ti Saulu ará Benjamini \li1 \v 1 Benjamini jẹ́ baba: \li2 Bela àkọ́bí rẹ̀, \li2 Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta, \li2 \v 2 Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún. \li1 \v 3 Àwọn ọmọ Bela ni, \li2 Adari, Gera, Abihudi, \v 4 Abiṣua, Naamani, Ahoa, \v 5 Gera, Ṣefufani àti Huramu. \li1 \v 6 Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati: \li2 \v 7 Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu. \li1 \v 8 A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara. \v 9 Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu, \v 10 Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé. \v 11 Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali. \li1 \v 12 Àwọn ọmọ Elipali: \li2 Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.) \v 13 Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò. \li1 \v 14 Ahio, Ṣasaki, Jeremoti, \v 15 Sebadiah, Aradi, Ederi \v 16 Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah. \li1 \v 17 Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi \v 18 Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali. \li1 \v 19 Jakimu, Sikri, Sabdi, \v 20 Elienai, Siletai, Elieli, \v 21 Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei. \li1 \v 22 Iṣipani Eberi, Elieli, \v 23 Abdoni, Sikri, Hanani, \v 24 Hananiah, Elamu, Anitotijah, \v 25 Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki. \li1 \v 26 Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah \v 27 Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu. \li4 \v 28 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu. \b \li1 \v 29 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. \li2 Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka, \v 30 àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu, \v 31 Gedori Ahio, Sekeri \v 32 pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu. \li1 \v 33 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali. \li1 \v 34 Ọmọ Jonatani: \li2 Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika. \li1 \v 35 Àwọn ọmọ Mika: \li2 Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi. \li2 \v 36 Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa. \v 37 Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀. \li1 \v 38 Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: \li2 Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli. \li1 \v 39 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki: \li2 Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta. \v 40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀. \li1 Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini. \b \c 9 \p \v 1 Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn. \s1 Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Jerusalẹmu \li4 \v 2 Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn ìránṣẹ́ ilé \nd Olúwa\nd*. \b \li4 \v 3 Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́: \li1 \v 4 Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda. \li1 \v 5 Àti nínú ará Ṣilo: \li2 Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀. \li1 \v 6 Ní ti ará Sera: \li2 Jeueli. \li4 Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690). \b \li4 \v 7 Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni: \li1 Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah; \li1 \v 8 Ibinaiah ọmọ Jerohamu; \li1 Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri; \li1 àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah. \li4 \v 9 Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé. \b \li4 \v 10 Ní ti àwọn àlùfáà: \li1 Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini; \li1 \v 11 Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run; \li1 \v 12 Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah; \li1 àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri. \li4 \v 13 Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run. \b \li4 \v 14 Ní ti àwọn ará Lefi: \li1 Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari; \li1 \v 15 Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu; \li1 \v 16 Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni; \li1 àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa. \b \li4 \v 17 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà: \li1 Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, \v 18 ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi. \li1 \v 19 Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé \nd Olúwa\nd*. \li1 \v 20 Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, \nd Olúwa\nd* sì wà pẹ̀lú rẹ̀. \li1 \v 21 Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé. \li4 \v 22 Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. \b \p Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. \v 23 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé \nd Olúwa\nd* ilé tí a pè ní àgọ́. \v 24 Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. \v 25 Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. \v 26 Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. \v 27 Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀. \p \v 28 Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. \v 29 Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. \v 30 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. \v 31 Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. \v 32 Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi. \p \v 33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé \nd Olúwa\nd*, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru. \p \v 34 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu. \s1 Ìdílé àti Ìrandíran Saulu \li1 \v 35 Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. \li2 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, \v 36 pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. \v 37 Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti. \v 38 Mikiloti jẹ́ baba Ṣimeamu, àwọn náà ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu. \li1 \v 39 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba a Saulu, àti Saulu baba a Jonatani, àti Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali. \li1 \v 40 Ọmọ Jonatani: \li2 Meribu-Baali, tí ó jẹ́ baba Mika. \li1 \v 41 Àwọn ọmọ Mika: \li2 Pitoni. Meleki, Tarea àti Ahasi. \li2 \v 42 Ahasi jẹ́ baba Jada, Jada jẹ́ baba Alemeti, Asmafeti, Simri, sì Simri jẹ́ baba Mosa. \v 43 Mosa jẹ́ baba Binea; Refaiah jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀. \li1 \v 44 Aseli ní ọmọ mẹ́fà, pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: \li2 Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli Ṣeariah, Obadiah àti Hanani, gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli. \c 10 \s1 Saulu gba ẹ̀mí ara rẹ̀ \p \v 1 Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. \v 2 Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. \v 3 Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́. \p \v 4 Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.” \p Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e. \v 5 Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú. \v 6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà. \p \v 7 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn. \p \v 8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. \v 9 Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. \v 10 Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni. \p \v 11 Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu, \v 12 gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje. \p \v 13 Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí \nd Olúwa\nd*, kò pa ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. \v 14 Kò sì béèrè lọ́wọ́ \nd Olúwa\nd*, bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese. \c 11 \s1 Dafidi di ọba lórí Israẹli \p \v 1 Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe. \v 2 Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ” \p \v 3 Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú \nd Olúwa\nd*, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* láti ọwọ́ Samuẹli. \s1 Dafidi borí Jerusalẹmu \p \v 4 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀. \v 5 Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi. \p \v 6 Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí. \p \v 7 Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi. \v 8 Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe. \v 9 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀. \s1 Dafidi alágbára ọkùnrin \p \v 10 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* ti ṣèlérí. \v 11 Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi: \p Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan. \p \v 12 Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Eleasari ọmọ Dodo àwọn ará Ahohi, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára. \v 13 Ó sì wà pẹ̀lú Dafidi ní Pasi-Dammimu nígbà tí àwọn ará Filistini kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà barle. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Filistini. \v 14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárín pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Filistini mọ́lẹ̀, \nd Olúwa\nd* sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn. \p \v 15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Refaimu. \v 16 Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu. \v 17 Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, “Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu?” \v 18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú \nd Olúwa\nd*. \v 19 “Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú. \p Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá. \p \v 20 Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta. \v 21 Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn. \p \v 22 Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò yìnyín dídì, ó sì pa kìnnìún kan \v 23 Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀. \v 24 Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta. \v 25 Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́. \b \li4 \v 26 Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí: \b \li1 Asaheli arákùnrin Joabu, \li1 Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu, \li1 \v 27 Ṣamotu ará Harori, \li1 Helesi ará Peloni \li1 \v 28 Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa, \li1 Abieseri láti Anatoti, \li1 \v 29 Sibekai ará Huṣati, \li1 láti ará Ahohi \li1 \v 30 Maharai ará Netofa, \li1 Heledi ọmọ Baanah ará Netofa, \li1 \v 31 Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini, \li1 Benaiah ará Piratoni, \li1 \v 32 Hurai láti àfonífojì Gaaṣi, \li1 Abieli ará Arbati, \li1 \v 33 Asmafeti ará Bahurimu \li1 Eliaba ará Ṣaalboni. \li1 \v 34 Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni \li1 Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari. \li1 \v 35 Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari, \li1 Elifali ọmọ Uri \li1 \v 36 Heferi ará Mekerati, \li1 Ahijah ará Peloni, \li1 \v 37 Hesro ará Karmeli \li1 Naarai ọmọ Esbai, \li1 \v 38 Joẹli arákùnrin Natani \li1 Mibari ọmọ Hagari, \li1 \v 39 Seleki ará Ammoni, \li1 Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah. \li1 \v 40 Ira ará Itri, \li1 Garebu ará Itri, \li1 \v 41 Uriah ará Hiti \li1 Sabadi ọmọ Ahlai. \li1 \v 42 Adina ọmọ Ṣisa ará Reubeni, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Reubeni, àti pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. \li1 \v 43 Hanani ọmọ Maaka. \li1 Jehoṣafati ará Mitini. \li1 \v 44 Ussia ará Asiterati, \li1 Ṣama àti Jeieli àwọn ọmọ Hotami ará Aroeri, \li1 \v 45 Jediaeli ọmọ Ṣimri, \li1 àti arákùnrin Joha ará Tisi \li1 \v 46 Elieli ará Mahafi \li1 Jeribai àti Joṣafia àwọn ọmọ Elnaamu, \li1 Itimah ará Moabu, \li1 \v 47 Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba. \c 12 \s1 Àwọn ọ̀gágun tí ó dúró ti Dafidi \li4 \v 1 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà. \v 2 Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini): \b \li1 \v 3 Ahieseri olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah: \li1 Jeṣieli àti Peleti ọmọ Asmafeti, \li1 Beraka, Jehu ará Anatoti. \v 4 Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; \li1 Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera, \v 5 Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti; \li1 \v 6 Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora; \li1 \v 7 àti Joẹla, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori. \b \p \v 8 Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè. \b \li1 \v 9 Eseri sì jẹ́ ìjòyè, \li1 Obadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́ẹ̀kẹta, \li1 \v 10 Miṣimana ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀karùnún \li1 \v 11 Attai ẹlẹ́ẹ̀kẹfà, Elieli èkeje, \li1 \v 12 Johanani ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án \li1 \v 13 Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá. \b \p \v 14 Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún (1,000). \v 15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn. \p \v 16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga. \v 17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.” \p \v 18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé, \q1 “Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi! \q2 Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese! \q1 Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, \q2 àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, \q3 nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” \p Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun. \p \v 19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”) \v 20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Manase. \v 21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. \v 22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run. \s1 Àwọn tókù darapọ̀ pẹ̀lú Dafidi ní Hebroni \li4 \v 23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd* ti sọ. \b \li1 \v 24 Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lẹ́gbẹ̀rin (6,800) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun. \li1 \v 25 Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé ọgọ́rùn-ún (7,100); \li1 \v 26 àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600), \v 27 pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (3,700) ènìyàn, \v 28 àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀; \li1 \v 29 àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà; \li1 \v 30 àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ogún ẹgbẹ̀rún ó le ẹgbẹ̀rin (20,800); \li1 \v 31 àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000). \li1 \v 32 Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà; àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn. \li1 \v 33 Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (50,000). \li1 \v 34 Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún (1,000) ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000). Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn. \li1 \v 35 Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá mẹ́tàlá (28,600). \li1 \v 36 Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì (40,000). \li1 \v 37 Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000). \b \li4 \v 38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́. \b \p Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba. \v 39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn. \v 40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli. \c 13 \s1 Gbígbé padà àpótí ẹ̀rí \p \v 1 Dafidi sì gbèrò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ ọgọ́rùn-ún \v 2 Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Israẹli pé, tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jíjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tókù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Israẹli àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọ pọ̀ sọ́dọ̀ wa. \v 3 Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Saulu. \v 4 Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn. \p \v 5 Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu. \v 6 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run \nd Olúwa\nd* tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù gòkè wá. \p \v 7 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ. \v 8 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè. \p \v 9 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. \v 10 Ìbínú \nd Olúwa\nd*, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run. \p \v 11 Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú \nd Olúwa\nd* ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Peresi-Usa. \p \v 12 Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi? \v 13 Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. \v 14 Àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, \nd Olúwa\nd* sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní. \c 14 \s1 Ilé àti ìdílé Dafidi \p \v 1 Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un. \v 2 Dafidi sì mọ Israẹli àti pé \nd Olúwa\nd* ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀. \p \v 3 Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin. \v 4 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni, \v 5 Ibhari, Eliṣua, Elifeleti, \v 6 Noga, Nefegi, Jafia, \v 7 Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti. \s1 Dafidi ṣẹ́gun àwọn ará Filistini \p \v 8 Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn. \v 9 Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu; \v 10 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé, “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” \p \nd Olúwa\nd* sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.” \p \v 11 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu. \v 12 Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná. \p \v 13 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì, \v 14 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, “Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká, kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi. \v 15 Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini.” \v 16 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri. \p \v 17 Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, \nd Olúwa\nd* sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀. \c 15 \s1 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu \p \v 1 Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. \v 2 Nígbà náà Dafidi wí pé, kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí \nd Olúwa\nd* yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé. \p \v 3 Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un. \b \li4 \v 4 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀. \b \li1 \v 5 Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati; \li2 Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \li1 \v 6 Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari; \li2 Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \li1 \v 7 Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni; \li2 Joẹli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \li1 \v 8 Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani; \li2 Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \li1 \v 9 Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hebroni; \li2 Elieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \li1 \v 10 Méjìléláàádọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli; \li2 Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. \b \p \v 11 Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joẹli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi. \v 12 Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un. \v 13 Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.” \v 14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli. \v 15 Nígbà náà ni àwọn Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd*. \p \v 16 Dafidi sọ fún àwọn olórí àwọn Lefi láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin olókùn, dùùrù, àti símbálì. \p \v 17 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Lefi yan Hemani ọmọ Joẹli; àti nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah, àti nínú àwọn ọmọ Merari arákùnrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah; \v 18 àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè. \p \v 19 Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan; \v 20 Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí \tl alamoti,\tl* \v 21 àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí \tl ṣeminiti.\tl* \v 22 Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀. \p \v 23 Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. \v 24 Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. \p \v 25 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú \nd Olúwa\nd* láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn. \v 26 Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú \nd Olúwa\nd*, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ. \v 27 Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun. \v 28 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú \nd Olúwa\nd* gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro. \p \v 29 Bí àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀. \c 16 \s1 Orin ọpẹ́ Dafidi \p \v 1 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. \v 2 Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ \nd Olúwa\nd*. \v 3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. \p \v 4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli. \v 5 Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. \v 6 Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run. \p \v 7 Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí \nd Olúwa\nd*. \q1 \v 8 Ẹ fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, ẹ pe orúkọ rẹ̀, \q2 ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe \q1 \v 9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, \q2 ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. \q1 \v 10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; \q2 jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin \nd Olúwa\nd* kí ó yọ̀. \q1 \v 11 Ẹ wá \nd Olúwa\nd* àti agbára rẹ̀; \q2 e wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. \b \q1 \v 12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, \q2 iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ. \q1 \v 13 A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀, \q2 àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn. \q1 \v 14 Òun ni \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa; \q2 ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé. \b \q1 \v 15 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, \q2 ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, \q1 \v 16 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, \q2 ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki. \q1 \v 17 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu, \q2 gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé: \q1 \v 18 “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. \q2 Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.” \b \q1 \v 19 Nígbà tí wọn kéré ní iye, \q2 wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀, \q1 \v 20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè \q2 láti ìjọba kan sí èkejì. \q1 \v 21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; \q2 nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí. \q1 \v 22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi; \q2 má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.” \b \q1 \v 23 Kọrin sí \nd Olúwa\nd* gbogbo ayé; \q2 ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. \q1 \v 24 Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, \q2 ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn. \b \q1 \v 25 Nítorí títóbi ni \nd Olúwa\nd* òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ; \q2 òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ. \q1 \v 26 Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, \q2 ṣùgbọ́n \nd Olúwa\nd* dá àwọn ọ̀run. \q1 \v 27 Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; \q2 agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀. \b \q1 \v 28 Fi fún \nd Olúwa\nd*, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, \q2 ẹ fi ògo àti ipá fún \nd Olúwa\nd*. \q1 \v 29 Fún \nd Olúwa\nd* ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; \q2 gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. \q1 Sìn \nd Olúwa\nd* nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. \q2 \v 30 Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! \q2 Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i. \b \q1 \v 31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; \q2 lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “\nd Olúwa\nd* jẹ ọba!” \q1 \v 32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; \q2 Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀! \q1 \v 33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, \q2 wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú \nd Olúwa\nd*, \q2 nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé. \b \q1 \v 34 Fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ó dára; \q2 ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé. \q1 \v 35 Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; \q2 kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, \q1 kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, \q2 kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.” \q1 \v 36 Olùbùkún ni \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, \q2 láé àti láéláé. \m Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin \nd Olúwa\nd*.” \b \p \v 37 Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. \v 38 Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. \p \v 39 Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ \nd Olúwa\nd* ní ibi gíga ní Gibeoni. \v 40 Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin \nd Olúwa\nd*, tí ó ti fún Israẹli. \v 41 Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún \nd Olúwa\nd*, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé \v 42 Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà. \p \v 43 Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀. \c 17 \s1 Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi \p \v 1 Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd* wà lábẹ́ àgọ́.” \p \v 2 Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.” \p \v 3 Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé: \pm \v 4 “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. \v 5 Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. \v 6 Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’ \pm \v 7 “Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí \nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. \v 8 Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. \v 9 Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. \v 10 Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín. \pm “ ‘Èmi sọ fún yín pé \nd Olúwa\nd* yóò kọ́ ilé kan fún yín, \v 11 nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. \v 12 Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. \v 13 Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. \v 14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ” \p \v 15 Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí. \s1 Àdúrà Dafidi \p \v 16 Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú \nd Olúwa\nd* ó sì wí pé, \pm “Ta ni èmi, \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? \v 17 Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run, ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run. \pm \v 18 “Kí ni ohun tí Dafidi tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìránṣẹ́ rẹ, \v 19 \nd Olúwa\nd*. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìlérí ńlá yìí hàn. \pm \v 20 “Kò sí ẹnìkan bí rẹ \nd Olúwa\nd*, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa. \v 21 Pẹ̀lú ta ni ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli—orílẹ̀-èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti láti ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹni tí ó gbàlà láti Ejibiti? \v 22 Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ \nd Olúwa\nd* sì ti di Ọlọ́run wọn. \pm \v 23 “Nísinsin yìí, \nd Olúwa\nd*, jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. \v 24 Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘\nd Olúwa\nd* àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ. \pm \v 25 “Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. \v 26 \nd Olúwa\nd*, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. \v 27 Nísinsin yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìránṣẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀síwájú ní ojú rẹ; nítorí ìwọ, \nd Olúwa\nd*, ti bùkún un, a ó sì bùkún un títí láéláé.” \c 18 \s1 Àwọn ìṣẹ́gun Dafidi \p \v 1 Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini. \p \v 2 Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá. \p \v 3 Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Soba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate. \v 4 Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà. \p \v 5 Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) wọn bọ lẹ̀. \v 6 Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. \nd Olúwa\nd* sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ. \p \v 7 Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. \v 8 Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ. \p \v 9 Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba. \v 10 Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá. \p \v 11 Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki. \p \v 12 Abiṣai ọmọ Seruiah lu ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ará Edomu bolẹ̀ ní àfonífojì Iyọ̀. \v 13 Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. \nd Olúwa\nd* fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ. \s1 Àwọn oníṣẹ́ Dafidi \p \v 14 Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀. \b \li1 \v 15 Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun; \li1 Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí; \li1 \v 16 Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà; \li1 Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé; \li1 \v 17 Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti; \li1 àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba. \c 19 \s1 Dafidi ṣẹ́gun àwọn ara Ammoni \p \v 1 Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. \v 2 Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀. \p Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i. \v 3 Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, “Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà.” \v 4 Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ. \p \v 5 Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dafidi nípa àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, “Dúró ní Jeriko títí tí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ẹ padà wá”. \p \v 6 Nígbà tí àwọn ará Ammoni sì ri pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dafidi, Hanuni àti àwọn ará Ammoni rán ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti Aramu-Naharaimu, Siria Maaka àti Soba. \v 7 Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun. \p \v 8 Ní gbígbọ́ eléyìí, Dafidi rán Joabu jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun ọkùnrin tí ó le jà. \v 9 Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀-èdè tí ó ṣí sílẹ̀. \p \v 10 Joabu ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun, bẹ́ẹ̀ ni o mu àwọn ọmọ-ogun tí ó dára ní Israẹli, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Siria. \v 11 Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Abiṣai arákùnrin rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ammoni. \v 12 Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́. \v 13 Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. \nd Olúwa\nd* yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀. \p \v 14 Nígbà náà Joabu àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Siria. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀. \v 15 Nígbà ti àwọn ará Ammoni ri pé àwọn ará Siria ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin rẹ̀ Abiṣai. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu padà lọ sí Jerusalẹmu. \p \v 16 Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Siria rí wí pé àwọn Israẹli ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Siria rékọjá odò Eufurate wá, pẹ̀lú Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun Hadadeseri, tí ó ń darí wọn. \p \v 17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi nípa èyí, ó pe gbogbo Israẹli jọ wọ́n sì rékọjá Jordani; Ó lọ síwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dafidi fa ìlà rẹ̀ láti bá àwọn ará Siria jagun wọ́n sì dojú ìjà kọ ọ́. \v 18 Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú. \p \v 19 Nígbà tí àwọn ẹrú Hadadeseri rí i wí pé Israẹli ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dafidi, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ rẹ̀. \p Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Siria kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ammoni lọ́wọ́ mọ́. \c 20 \s1 Dafidi ṣẹ́gun Rabba \p \v 1 Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Joabu ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ammoni ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rabba. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dafidi dúró sí Jerusalẹmu Joabu kọlu Rabba, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun. \v 2 Dafidi mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n rẹ̀ dàbí i tálẹ́ǹtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye. A sì gbé e ka orí Dafidi. Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà. \v 3 Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dafidi ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ammoni. Nígbà náà, Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu. \s1 Ogun pẹ̀lú àwọn ará Filistini \p \v 4 Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri pẹ̀lú àwọn ará Filistini, ní àkókò yìí ni Sibekai ará Huṣati pa Sipai, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Refaimu, àti àwọn ará Filistini ni a ṣẹ́gun. \p \v 5 Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Filistini, Elhanani ọmọ Jairi pa Lahmi arákùnrin Goliati ará Gitti, ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunṣọ. \p \v 6 Síbẹ̀síbẹ̀ nínú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gati, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Rafa. \v 7 Nígbà tí ó fi Israẹli ṣẹ̀sín, Jonatani ọmọ Ṣimea, arákùnrin Dafidi sì pa á. \p \v 8 Wọ̀nyí ni ìran ọmọ Rafa ní Gati, wọ́n sì ṣubú sí ọwọ́ Dafidi àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. \c 21 \s1 Dafidi ṣe ètò ìkànìyàn \p \v 1 Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli. \v 2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.” \p \v 3 Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí \nd Olúwa\nd* kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?” \p \v 4 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu. \v 5 Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún (470,000) ọkùnrin tí ń kọ́ idà. \p \v 6 Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un. \v 7 Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli. \p \v 8 Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi. \p \v 9 \nd Olúwa\nd* sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé. \v 10 “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ” \p \v 11 Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni \nd Olúwa\nd* wí: ‘Yan fún ara rẹ. \v 12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà \nd Olúwa\nd* ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli \nd Olúwa\nd* láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.” \p \v 13 Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ \nd Olúwa\nd* nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.” \p \v 14 Bẹ́ẹ̀ ni \nd Olúwa\nd* rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn. \v 15 Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, \nd Olúwa\nd* sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli \nd Olúwa\nd* náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. \p \v 16 Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli \nd Olúwa\nd* dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀. \p \v 17 Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.” \p \v 18 Nígbà náà angẹli \nd Olúwa\nd* náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún \nd Olúwa\nd* lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. \v 19 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ \nd Olúwa\nd*. \p \v 20 Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́. \v 21 Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi. \p \v 22 Dafidi sì wí fún Arauna pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó ni ibi ìpakà rẹ kí èmi kí ó sì lè tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún \nd Olúwa\nd*, ìwọ ó sì fi fún mi ni iye owó rẹ̀ pípé, kí a lè dá àjàkálẹ̀-ààrùn dúró lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.” \p \v 23 Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.” \p \v 24 Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún \nd Olúwa\nd*, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.” \p \v 25 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà. \v 26 Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún \nd Olúwa\nd* níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe \nd Olúwa\nd*, \nd Olúwa\nd* sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun. \p \v 27 Nígbà náà \nd Olúwa\nd* sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀. \v 28 Ní àkókò náà nígbà tí Dafidi sì rí wí pé \nd Olúwa\nd* ti dá a lóhùn lórí ilẹ̀ ìpakà ti Arauna ará Jebusi, ó sì rú ẹbọ sísun níbẹ̀. \v 29 Àgọ́ \nd Olúwa\nd* tí Mose ti ṣe ní aginjù, àti pẹpẹ ẹbọ sísun wà lórí ibi gíga ní Gibeoni ní àkókò náà. \v 30 Ṣùgbọ́n Dafidi kò lè lọ síwájú rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí tí ó bẹ̀rù nípa idà ọwọ́ angẹli \nd Olúwa\nd*. \c 22 \p \v 1 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.” \s1 Ìmúrasílẹ̀ fún ilé tí a kọ́ fún ìsìn Ọlọ́run \p \v 2 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. \v 3 Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. \v 4 Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi. \p \v 5 Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún \nd Olúwa\nd* gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú. \p \v 6 Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli. \v 7 Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mi. \v 8 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ \nd Olúwa\nd* tọ̀ mí wá wí pé, ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. \v 9 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. \v 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’ \p \v 11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí \nd Olúwa\nd* wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. \v 12 Kí \nd Olúwa\nd* kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run mọ́. \v 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti \nd Olúwa\nd* ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́. \p \v 14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé \nd Olúwa\nd* ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. \v 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. \v 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí \nd Olúwa\nd* wà pẹ̀lú rẹ.” \p \v 17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. \v 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú \nd Olúwa\nd* àti níwájú àwọn ènìyàn. \v 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú \nd Olúwa\nd* àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé \nd Olúwa\nd* tí a o kọ́ fún orúkọ \nd Olúwa\nd*.” \c 23 \s1 Àwọn ará Lefi \p \v 1 Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli. \p \v 2 Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. \v 3 Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000). \v 4 Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún \nd Olúwa\nd* àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. \v 5 Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin \nd Olúwa\nd* pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí. \b \li4 \v 6 Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari. \s1 Àwọn ọmọ Gerṣoni \li1 \v 7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: \li2 Laadani àti Ṣimei. \li1 \v 8 Àwọn ọmọ Laadani \li2 Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn. \li1 \v 9 Àwọn ọmọ Ṣimei: \li2 Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. \li2 Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani. \li1 \v 10 Àti ọmọ Ṣimei: \li2 Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. \li2 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn. \li2 \v 11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan. \s1 Àwọn ará Kohati \li1 \v 12 Àwọn ọmọ Kohati: \li2 Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn. \li1 \v 13 Àwọn ọmọ Amramu. \li2 Aaroni àti Mose. \li2 A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú \nd Olúwa\nd*, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. \v 14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi. \li1 \v 15 Àwọn ọmọ Mose: \li2 Gerṣomu àti Elieseri. \li1 \v 16 Àwọn ọmọ Gerṣomu: \li2 Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́. \li1 \v 17 Àwọn ọmọ Elieseri: \li2 Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́. \li2 Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye. \li1 \v 18 Àwọn ọmọ Isari: \li2 Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́. \li1 \v 19 Àwọn ọmọ Hebroni: \li2 Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, \li2 Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin. \li1 \v 20 Àwọn ọmọ Usieli: \li2 Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì. \s1 Àwọn ará Merari \li1 \v 21 Àwọn ọmọ Merari: \li2 Mahili àti Muṣi. \li1 Àwọn ọmọ Mahili: \li2 Eleasari àti Kiṣi. \li2 \v 22 Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn. \li1 \v 23 Àwọn ọmọ Muṣi: \li2 Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn. \b \li4 \v 24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé \nd Olúwa\nd*. \v 25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé, \v 26 àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀.” \v 27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. \b \p \v 28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé \nd Olúwa\nd*: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé \nd Olúwa\nd*. \v 29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n. \v 30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin \nd Olúwa\nd*. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. \v 31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún \nd Olúwa\nd* ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú \nd Olúwa\nd* lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn. \p \v 32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé \nd Olúwa\nd*. \c 24 \s1 Pínpín àwọn àlùfáà \p \v 1 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. \p Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. \v 2 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. \v 3 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. \v 4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. \v 5 Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari. \p \v 6 Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari. \b \li1 \v 7 Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, \li1 èkejì sí Jedaiah, \li1 \v 8 ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, \li1 ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu, \li1 \v 9 ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, \li1 ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini, \li1 \v 10 èkeje sì ni Hakosi, \li1 ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah, \li1 \v 11 ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, \li1 ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah, \li1 \v 12 ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, \li1 ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu, \li1 \v 13 ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, \li1 ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu, \li1 \v 14 ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, \li1 ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri, \li1 \v 15 ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, \li1 èkejìdínlógún sì ni Hafisesi, \li1 \v 16 ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, \li1 ogún sì ni Jeheskeli, \li1 \v 17 ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, \li1 ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli, \li1 \v 18 ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, \li1 ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah. \b \p \v 19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un. \s1 Ìyókù nínú àwọn ọmọ Lefi \li4 \v 20 Ìyókù àwọn ọmọ Lefi. \b \li1 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli \li2 láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah. \li1 \v 21 Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́. \li1 \v 22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti; \li2 láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati. \li1 \v 23 Àwọn ọmọ Hebroni: \li2 Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin. \li1 \v 24 Àwọn ọmọ Usieli: Mika; \li2 nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri. \li1 \v 25 Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi; \li2 nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah. \li1 \v 26 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. \li2 Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno. \li1 \v 27 Àwọn ọmọ Merari. \li2 Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri. \li1 \v 28 Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ. \li1 \v 29 Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli. \li1 \v 30 Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti. \b \li4 Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. \b \p \v 31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké. \c 25 \s1 Àwọn akọrin \p \v 1 Pẹ̀lúpẹ̀lú Dafidi àti àwọn olórí àwọn ọmọ-ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Asafu, Hemani àti Jedutuni fún ìsìn àsọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn àti kimbali. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí. \b \li1 \v 2 Nínú àwọn ọmọ Asafu: \li2 Sakkuri, Josẹfu, Netaniah àti Asarela, àwọn ọmọ Asafu ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó Asafu, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìbojútó ọba. \li1 \v 3 Gẹ́gẹ́ bí ti Jedutuni, nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀: \li2 Gedaliah, Seri, Jeṣaiah, Ṣimei, Haṣabiah àti Mattitiah, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jedutuni, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti láti yin \nd Olúwa\nd*. \li1 \v 4 Gẹ́gẹ́ bí ti Hemani, nínú àwọn ọmọ rẹ̀: \li2 Bukkiah, Mattaniah, Usieli, Ṣubaeli àti Jerimoti; Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, àti Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu. \v 5 Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hemani àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hemani ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta. \b \p \v 6 Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ni wọ́n wà lábẹ́ ìbojútó àwọn baba wọn fún ohun èlò orin ilé \nd Olúwa\nd*, pẹ̀lú kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù, fún ìsìn ilé Olúwa. \p Asafu, Jedutuni àti Hemani sì wà lábẹ́ ọba. \v 7 Àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún \nd Olúwa\nd*, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ (288). \v 8 Kékeré àti àgbà bákan náà, olùkọ́ àti gẹ́gẹ́ bí ti akẹ́kọ̀ọ́, ṣẹ́ kèké fún iṣẹ́ wọn. \b \li1 \v 9 Kèké èkínní èyí tí ó jẹ́ ti Asafu, jáde sí Josẹfu, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 èkejì sì ni Gedaliah, òun àti àwọn ìdílé rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, méjìlá \li1 \v 10 ẹlẹ́ẹ̀kẹta sí Sakkuri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé, méjìlá \li1 \v 11 ẹlẹ́ẹ̀kẹrin sí Isiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 12 ẹlẹ́ẹ̀karùnún sí Netaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 13 ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sí Bukkiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 14 ẹlẹ́ẹ̀keje sí Jasarela, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 15 ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí Jeṣaiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 16 ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án sí Mattaniah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 17 ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá sí Ṣimei, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ jẹ́, méjìlá \li1 \v 18 ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá sí Asareeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 19 ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sí Haṣabiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 20 ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlá sí Ṣubaeli, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 21 ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sí Mattitiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 22 ẹlẹ́ẹ̀kẹẹ̀dógún sí Jerimoti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 23 ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlógún sí Hananiah, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 24 ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlógún sí Joṣbekaṣa, àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 25 ẹlẹ́ẹ̀kejìdínlógún sí Hanani, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 26 ẹlẹ́ẹ̀kọkàndínlógún sí Malloti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 27 ogún sí Eliata, àwọn ọmọ rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 28 ẹlẹ́ẹ̀kọkànlélógún sí Hotiri, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 29 ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún sí Giddalti, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 30 ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlélógún sí Mahasiotu, àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá \li1 \v 31 ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlélógún sí Romamtieseri àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ìdílé rẹ̀ sì jẹ́, méjìlá. \c 26 \s1 Àwọn olùtọ́jú ẹnu ọnà \li4 \v 1 Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. \b \li4 Láti ìran Kora: \li1 Meṣelemiah ọmọ Kore, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Asafu. \v 2 Meṣelemiah ní àwọn ọmọkùnrin: \li2 Sekariah àkọ́bí, Jediaeli ẹlẹ́ẹ̀kejì, \li2 Sebadiah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Jatnieli ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, \li2 \v 3 Elamu ẹlẹ́ẹ̀karùnún, Jehohanani ẹlẹ́ẹ̀kẹfà \li2 àti Elihoenai ẹlẹ́ẹ̀keje. \li1 \v 4 Obedi-Edomu ni àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú: \li2 Ṣemaiah àkọ́bí, Jehosabadi ẹlẹ́ẹ̀kejì, \li2 Joah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Sakari ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, \li2 Netaneli ẹlẹ́ẹ̀karùnún, \v 5 Ammieli ẹ̀kẹfà, \li2 Isakari èkeje àti Peulltai ẹ̀kẹjọ. \li2 (Nítorí tí Ọlọ́run ti bùkún Obedi-Edomu). \li1 \v 6 Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára. \v 7 Àwọn ọmọ Ṣemaiah: \li2 Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi; \li2 àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára. \li4 \v 8 Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀. \li4 \v 9 Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn. \b \li1 \v 10 Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin: \li2 Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́. \li2 \v 11 Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta \li2 àti Sekariah ẹ̀kẹrin. \li4 Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀. \b \li4 \v 12 Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe. \v 13 Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó. \li1 \v 14 Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah. \li1 Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. \li1 \v 15 Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù bọ́ sí ọ̀dọ̀ Obedi-Edomu, kèké fún ilé ìṣúra sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ̀. \li1 \v 16 Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣaleketi ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣuppimu àti Hosa. \b \li4 Olùṣọ́ wà ní ẹ̀bá olùṣọ́. \li1 \v 17 Àwọn ará Lefi mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà-oòrùn, \li1 mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, \li1 mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúúsù \li1 àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra. \li1 \v 18 Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀. \b \li4 \v 19 Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ Kora àti Merari. \s1 Àwọn afowópamọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìyókù \p \v 20 Láti inú àwọn ọmọ Lefi, Ahijah ni ó wà lórí ìṣúra ti ilé Ọlọ́run àti lórí ìṣúra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a yà sí mímọ́. \p \v 21 Àwọn ìran ọmọ Laadani tí wọn jẹ́ ará Gerṣoni nípasẹ̀ Laadani àti tí wọn jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Laadani ará Gerṣoni ni Jehieli. \v 22 Àwọn ọmọ Jehieli, Setamu àti arákùnrin rẹ̀ Joẹli. Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé \nd Olúwa\nd*. \b \li4 \v 23 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Amramu, àwọn ará Isari, àwọn ará Hebroni àti àwọn ará Usieli. \b \li2 \v 24 Ṣubaeli, ìran ọmọ Gerṣomu ọmọ Mose jẹ́ olórí tí ó bojútó ilé ìṣúra. \v 25 Àwọn ìbátan rẹ̀ nípasẹ̀ Elieseri: Rehabiah ọmọ rẹ̀, Jeṣaiah ọmọ rẹ̀, Joramu ọmọ rẹ̀, Sikri ọmọ rẹ̀, Ṣelomiti ọmọ rẹ̀. \li2 \v 26 Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀ jẹ́ alábojútó ilé ìṣúra fún àwọn ohun tí à ti yà sọ́tọ̀ nípa ọba Dafidi, nípasẹ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti nípasẹ̀ alákòóso ọmọ-ogun mìíràn. \v 27 Díẹ̀ nínú ìkógun tí wọ́n kó nínú ogun ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún títún ilé \nd Olúwa\nd* ṣe. \v 28 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Samuẹli aríran láti nípasẹ̀ Saulu ọmọ Kiṣi, Abneri ọmọ Neri àti Joabu ọmọ Seruiah gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣelomiti àti àwọn ìbátan rẹ̀. \li2 \v 29 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Isari: \li2 Kenaniah àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni a pín iṣẹ́ ìsìn fún kúrò ní apá ilé \nd Olúwa\nd*, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣẹ́ àti àwọn adájọ́ lórí Israẹli. \li2 \v 30 Láti ọ̀dọ̀ àwọn Hebroni: \li2 Haṣabiah àti àwọn ìbátan rẹ̀ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán (17,000) ọkùnrin alágbára ní ó dúró ni Israẹli, ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani fún gbogbo iṣẹ́ \nd Olúwa\nd* àti fún iṣẹ́ ọba. \v 31 Ní ti àwọn ará Hebroni, Jeriah jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, ní ti ìdílé wọn. \li2 Ní ọdún kẹrin ìjọba Dafidi, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrín àwọn ará Hebroni ni a rí ní Jaseri ní Gileadi. \v 32 Jeriah ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (2,700) ìbátan, tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbára àti olórí àwọn ìdílé ọba Dafidi sì fi wọ́n ṣe àkóso lórí àwọn ará Reubeni àwọn ará Gadi àti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase fún gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jọ mọ́ ti Ọlọ́run àti fún ọ̀ràn ti ọba. \c 27 \s1 Ìpín ti àwọn ọmọ-ogun \li4 \v 1 Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin. \b \li1 \v 2 Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. \v 3 Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní. \li1 \v 4 Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. \li1 \v 5 Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. \v 6 Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀. \li1 \v 7 Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 8 Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. \li1 \v 9 Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 10 Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 11 Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 12 Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 13 Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. \li1 \v 14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. \li1 \v 15 Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. \s1 Àwọn ìjòyè ti ẹ̀yà náà \li4 \v 16 Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: \b \li1 lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri; \li1 lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka; \li1 \v 17 lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli; \li1 lórí Aaroni: Sadoku; \li1 \v 18 lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi; \li1 lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli; \li1 \v 19 lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah; \li1 lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli; \li1 \v 20 lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah; \li1 lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah; \li1 \v 21 lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; \li1 lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri; \li1 \v 22 lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. \b \li4 Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli. \b \p \v 23 Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí \nd Olúwa\nd* ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run. \v 24 Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi. \s1 Àwọn alábojútó ọba \li1 \v 25 Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. \li1 Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́. \li1 \v 26 Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà. \li1 \v 27 Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. \li1 Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí. \li1 \v 28 Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. \li1 Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi. \li1 \v 29 Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni. \li1 Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀. \li1 \v 30 Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. \li1 Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. \li1 \v 31 Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran. \li4 Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi. \b \li1 \v 32 Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. \li1 Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba. \li1 \v 33 Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba. \li1 Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba. \li4 \v 34 (Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.) \li1 Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba. \c 28 \s1 Àwọn èrò Dafidi lórí ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Dafidi pe gbogbo àwọn oníṣẹ́ ti Israẹli láti péjọ ní Jerusalẹmu. Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà, àwọn alákòóso ìpín nínú iṣẹ́ bí ọba, àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí bíbojútó gbogbo àwọn ẹrù àti ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ààfin àwọn oníṣẹ́ ààfin, àwọn ọkùnrin alágbára àti gbogbo àwọn ògbójú jagunjagun lápapọ̀. \p \v 2 Ọba Dafidi dìde dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀, o sì wí pé, “Fetísílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni lọ́kàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí tí \nd Olúwa\nd* fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ. \v 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀.’ \p \v 4 “Síbẹ̀ \nd Olúwa\nd*, Ọlọ́run Israẹli yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Israẹli, títí láé. Ó yan Juda gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Juda, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Israẹli. \v 5 Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú \nd Olúwa\nd* ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Solomoni láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba ti \nd Olúwa\nd* lórí Israẹli. \v 6 Ó wí fún mi pé, Solomoni ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a rẹ̀. \v 7 Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí. \p \v 8 “Bẹ́ẹ̀ ni, nísinsin yìí, èmi pàṣẹ fún ọ ní ojú gbogbo Israẹli àti ní ti ìpéjọpọ̀ tí \nd Olúwa\nd*, àti ní etí ìgbọ́ Ọlọ́run wa. Ṣọ́ra kó o sì tẹ̀lé gbogbo òfin \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run rẹ kí ìwọ kí ó le jogún ilẹ̀ dáradára yìí, kí o sì mú un lọ síwájú gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ fún àwọn ìran ọmọ rẹ títí láé. \p \v 9 “Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí \nd Olúwa\nd* ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé. \v 10 Gbèrò báyìí nítorí tí \nd Olúwa\nd* ti yàn ọ́ láti kọ́ ilé \nd Olúwa\nd* gẹ́gẹ́ bí ilé tí a yà sí mímọ́ fún \nd Olúwa\nd*. Jẹ́ alágbára kí ó sì ṣe iṣẹ́ náà.” \p \v 11 Nígbà náà ni Dafidi fi àpẹẹrẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ ti ìloro àti ti ilé \nd Olúwa\nd* náà, kíkọ́ ọ rẹ̀, àti ti ibi ìṣúra rẹ̀, àti ti iyàrá òkè rẹ̀, àti ti ìyẹ̀wù rẹ̀ àti ti ibùjókòó àánú. \v 12 Ó fún un ní àwọn ètò gbogbo èyí tí ẹ̀mí ti fi sí ọkàn rẹ̀ fún ti ààfin ilé \nd Olúwa\nd* àti gbogbo yàrá tí ó yíká fún ìṣúra ilé Ọlọ́run àti fún ìṣúra fún ohun yíyà sọ́tọ̀. \v 13 Ó fún un ní àwọn ìlànà fún ìpín ti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àti fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn nínú ilé \nd Olúwa\nd* àti fún gbogbo ohun èlò tí wọn ó lò nínú ìsìn rẹ̀. \v 14 Ó yàn ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà tí a ó lò níbi oríṣìí ìsìn, àti ìwọ̀n fàdákà fún gbogbo ohun èlò fàdákà tí a ó lò fún oríṣìí ìsìn, \v 15 ìwọ̀n wúrà fún ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn, fún ìwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdúró fìtílà àti fìtílà wọn; àti ìwọ̀n fàdákà ìdúró fìtílà fàdákà àti àwọn fìtílà rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlò ti gbogbo ìdúró fìtílà. \v 16 Ìwọ̀n ti wúrà fun tábìlì, tábìlì fún àkàrà tí a yà sọ́tọ̀; ìwọ̀n fàdákà fún àwọn tábìlì fàdákà; \v 17 ìwọ̀n kìkì wúrà fún àwọn àmúga ìjẹun, àwọn ìbùwọ́n ọpọ́n àti àwọn ìkòkò ìpọnmi; ìwọ̀n wúrà fún gbogbo àwopọ̀kọ́ fàdákà; \v 18 àti ìwọ̀n ìdá wúrà fún pẹpẹ tùràrí ó fún un ní ètò fún kẹ̀kẹ́, ìyẹn ni pé àwọn ìdúró kérúbù wúrà tí wọ́n tan iye wọn ká, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí \nd Olúwa\nd*. \p \v 19 “Gbogbo èyí,” ni Dafidi wí pé, “Èmi ní kíkọ sílẹ̀ láti ọwọ́ \nd Olúwa\nd* sórí mi, ó sì fún mí ní ìmọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ ètò yìí.” \p \v 20 Dafidi tún sọ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára kí o sì gbóyà, kí o sì ṣe iṣẹ́ náà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí dààmú, nítorí \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ. Òun kì yóò sì já ọ kule tàbí kọ ọ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ní ti ilé \nd Olúwa\nd* yóò fi parí. \v 21 Ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ṣetán fún gbogbo iṣẹ́ ilé \nd Olúwa\nd*. Gbogbo ọkùnrin tí ó ní ìfẹ́ sí i tí ó sì ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn yóò gbọ́rọ̀ sí gbogbo àṣẹ rẹ.” \c 29 \s1 Ẹ̀bùn fún kíkọ́ ilé \nd Olúwa\nd* \p \v 1 Nígbà náà, ọba Dafidi sọ fún gbogbo àpéjọ pé, “Ọmọ mi Solomoni, èyí tí Ọlọ́run ti yàn, sì kéré ó sì jẹ́ aláìmòye. Iṣẹ́ náà tóbi, nítorí ìkọ́lé bí ti ààfin kì í ṣe fún ènìyàn ṣùgbọ́n fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run. \v 2 Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. \v 3 Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti \nd Olúwa\nd* yìí, \v 4 ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) tálẹ́ǹtì wúrà, ti wúrà Ofiri àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, fún bíbo àwọn ògiri ilé náà. \v 5 Fún iṣẹ́ wúrà àti fàdákà náà, àti fún oríṣìí iṣẹ́ ti ó yẹ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn tí ó ní òye oríṣìíríṣìí iṣẹ́. Nísinsin yìí, ta ni ó ní ìfẹ́ sí yíya ará rẹ̀ sọ́tọ̀ lónìí sí \nd Olúwa\nd*?” \p \v 6 Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i. \v 7 Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin. \v 8 Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé \nd Olúwa\nd* ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. \v 9 Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí \nd Olúwa\nd*. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi. \s1 Àdúrà Dafidi \p \v 10 Dafidi yin \nd Olúwa\nd* níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, \q1 “Ìyìn ni fún Ọ, \nd Olúwa\nd*, \q2 Ọlọ́run baba a wa Israẹli, \q2 láé àti láéláé. \q1 \v 11 Tìrẹ \nd Olúwa\nd* ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn \q2 àti ọláńlá àti dídán, \q2 nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. \q1 Tìrẹ \nd Olúwa\nd* ni ìjọba; \q2 a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. \q1 \v 12 Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; \q2 ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. \q1 Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti \q2 láti fi agbára fún ohun gbogbo. \q1 \v 13 Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, \q2 a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo. \p \v 14 “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. \v 15 Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. \v 16 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé \nd Olúwa\nd* fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. \v 17 Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsin yìí èmi ti rí i pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́. \v 18 \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ. \v 19 Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.” \p \v 20 Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, “Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run yín.” Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún \nd Olúwa\nd* Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún \nd Olúwa\nd* àti ọba. \s1 A yan Solomoni gẹ́gẹ́ bí ọba \p \v 21 Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí \nd Olúwa\nd*, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli. \v 22 Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú \nd Olúwa\nd* ní ọjọ́ náà. \p Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú \nd Olúwa\nd* láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà. \v 23 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ \nd Olúwa\nd* gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. \v 24 Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dafidi tẹrí ara wọn ba fún ọba Solomoni. \p \v 25 \nd Olúwa\nd* gbé Solomoni ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Israẹli, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọláńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú rẹ̀ tí ó jẹ lórí Israẹli. \s1 Ikú Dafidi \p \v 26 Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. \v 27 Ó jẹ ọba lórí Israẹli fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jẹ ọba ní Hebroni, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. \v 28 Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Solomoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. \p \v 29 Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dafidi, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Samuẹli aríran, ìwé ìrántí ti Natani wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gadi aríran, \v 30 lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí rẹ̀, àti lórí Israẹli, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà.